JEREMAYA 8
8
1“Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo kó egungun àwọn ọba Juda jáde kúrò ninu ibojì wọn, ati egungun àwọn ìjòyè ibẹ̀; ati ti àwọn alufaa, ati ti àwọn wolii, ati ti àwọn ará Jerusalẹmu. 2Wọn óo fọ́n wọn dà sílẹ̀ ninu oòrùn, ati lábẹ́ òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n ní ìfẹ́ sí, tí wọ́n sì sìn; àwọn ohun tí wọn ń wá kiri, tí wọn ń ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń bọ. A kò ní kó egungun wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní sin wọ́n. Wọn óo dàbí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí ilẹ̀. 3Yóo sàn kí àwọn tí ó bá kù ninu ìran burúkú yìí kú ju kí wọ́n wà láàyè lọ, ní ibikíbi tí mo bá lé wọn lọ. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Ẹ̀ṣẹ̀ ati Ìjìyà
4OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé,
“Ṣé bí eniyan bá ṣubú
kì í tún dìde mọ́?
Àbí bí eniyan bá ṣìnà,
kì í pada mọ́?
5Kí ló dé tí àwọn eniyan wọnyi fi yipada
kúrò lọ́dọ̀ mi,
tí wọn ń lọ láì bojúwẹ̀yìn?
Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni wọ́n sì wawọ́ mọ́;
wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi.
6Mo tẹ́tí sílẹ̀ kí n gbọ́ tiwọn,
ṣugbọn wọn kò sọ̀rọ̀ rere.
Kò sí ẹni tí ó kẹ́dùn iṣẹ́ ibi rẹ̀,
kí ó wí pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’
Olukuluku tẹ̀ sí ọ̀nà tí ó wù ú,
bí ẹṣin tí ń sáré lọ ojú ogun.
7Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ sì ni àdàbà, ati lékèélékèé, ati alápàáǹdẹ̀dẹ̀;
wọ́n mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada.
Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò mọ òfin OLUWA.
8Báwo ni ẹ ṣe lè wí pé,
‘Ọlọ́gbọ́n ni wá,
a sì mọ òfin OLUWA?’
Ṣugbọn àwọn akọ̀wé ti fi gègé irọ́ wọn sọ ọ́ di èké.
9Ojú yóo ti àwọn ọlọ́gbọ́n:
ìdààmú yóo bá wọn,
ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.
Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀,
ọgbọ́n wo ni ó kù tí wọ́n gbọ́n?
10Nítorí náà, n óo fi aya wọn fún ẹlòmíràn,
n óo fi oko wọn fún àwọn tí yóo ṣẹgun wọn.
Nítorí pé láti orí àwọn mẹ̀kúnnù,
títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki,
gbogbo wọn ni wọ́n ń lépa èrè àjẹjù.
Láti orí wolii títí kan alufaa, èké ni gbogbo wọn.
11Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jinná,#Isi 13:10
wọ́n ń kígbe pé, ‘Alaafia ni, alaafia ni,’
bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí alaafia.
12Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n#Jer 6:12-15
nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́?
Rárá o, ojú kì í tì wọ́n,
nítorí pé wọn kò lójútì.
Nítorí náà àwọn náà óo ṣubú
nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú,
a óo bì wọ́n ṣubú
nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà,
OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
13“Ní àkókò ìkórè, kò ní sí èso lórí àjàrà,
igi ọ̀pọ̀tọ́ kò ní ní èso lórí,
àwọn ewé pàápàá yóo gbẹ,
ohun tí mo fún wọn yóo di ti ẹlòmíràn.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
14Àwọn eniyan Ọlọrun bá dáhùn pé,
“Kí ló dé tí a fi jókòó jẹ̀kẹ̀tẹ̀?
Ẹ jẹ́ kí á kó ara wa jọ,
kí á sá lọ sí àwọn ìlú olódi,
kí á sì parun sibẹ;
nítorí OLUWA Ọlọrun wa ti fi wá lé ìparun lọ́wọ́,
ó ti fún wa ní omi tí ó ní májèlé mu,
nítorí pé a ti ṣẹ̀ ẹ́.
15À ń retí alaafia,
ṣugbọn ire kankan kò dé.
Àkókò ìwòsàn ni à ń retí,
ṣugbọn ìpayà ni a rí.
16Ẹ gbọ́ bí ẹṣin wọn tí ń fọn imú, ní ilẹ̀ Dani;
gbogbo ilẹ̀ ń mì tìtì nítorí ìró yíyan ẹṣin wọn.
Wọ́n wá run ilẹ̀ náà,
ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,
ati ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.”
17OLUWA ní, “Wò ó! N óo rán ejò sí ààrin yín:
paramọ́lẹ̀ tí kò ní gbóògùn;
wọn yóo sì bù yín jẹ.”
Jeremaya Káàánú fún Àwọn Eniyan Rẹ̀
18Ìbànújẹ́ mi pọ̀ kọjá ohun tí ó ṣe é wòsàn,
àárẹ̀ mú ọkàn mi.
19Ẹ gbọ́ igbe àwọn eniyan mi
jákèjádò ilẹ̀ náà tí wọn ń bèèrè pé,
“Ṣé OLUWA kò sí ní Sioni ni?
Tabi ọba rẹ̀ kò sí ninu rẹ̀ ni?”
OLUWA, ọba wọn dáhùn pé,
“Kí ló dé tí wọn ń fi ère wọn mú mi bínú,
pẹlu àwọn oriṣa ilẹ̀ àjèjì tí wọn ń bọ?”
20Àwọn eniyan ní, “Ìkórè ti parí,
àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn ti kọjá,
sibẹ a kò rí ìgbàlà.”
21Nítorí ọgbẹ́ àwọn eniyan mi ni ọkàn mi ṣe gbọgbẹ́.
Mò ń ṣọ̀fọ̀, ìdààmú sì bá mi.
22Ṣé kò sí ìwọ̀ra ní Gileadi ni?
Àbí kò sí oníwòsàn níbẹ̀?
Kí ló dé tí àìsàn àwọn eniyan mi kò sàn?
Currently Selected:
JEREMAYA 8: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010