YouVersion Logo
Search Icon

JEREMAYA 12

12
1Olódodo ni ọ́, OLUWA,
nígbà tí mo bá ń fẹjọ́ sùn ọ́;
sibẹ n óo ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ.
Kí ló dé tí nǹkan ń dára fún àwọn eniyan burúkú?
2O gbìn wọ́n, wọ́n ta gbòǹgbò;
wọ́n dàgbà, wọ́n so èso;
orúkọ rẹ kò jìnnà sẹ́nu wọn,
ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí ọ.
3Ṣugbọn ìwọ OLUWA mọ̀ mí,
O rí mi, o sì ti yẹ ọkàn mi wò
o mọ èrò mi sí ọ.
Fà wọ́n jáde bí aguntan tí wọn ń mú lọ pa,
yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìparun.
4Yóo ti pẹ́ tó, tí ilẹ̀ náà yóo máa ṣọ̀fọ̀,
tí koríko oko yóo rọ?
Nítorí iṣẹ́ burúkú àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀,
àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ ṣègbé,
nítorí àwọn eniyan ń wí pé,
“Kò ní rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wa.”
5OLUWA ní,
“Bí o bá àwọn tí ń fi ẹsẹ̀ sáré sáré, tí ó bá rẹ̀ ọ́,
báwo ni o ṣe lè bá ẹṣin sáré?
Bí o bá sì ń ṣubú ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú,
báwo ni o óo ti ṣe nígbà tí o bá dé aṣálẹ̀ Jọdani?
6Nítorí pé àwọn arakunrin rẹ pàápàá
ati àwọn ará ilé baba rẹ
ti hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí ọ;
àwọn gan-an ni wọ́n ń ṣe èké rẹ:
Má gbẹ́kẹ̀lé wọn,
bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rere sí ọ.”
OLUWA Káàánú Àwọn Eniyan Rẹ̀
7OLUWA wí pé,
“Mo ti kọ ilé mi sílẹ̀;
mo ti kọ ogún tí a pín fún mi sílẹ̀.
Mo ti fa ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
8Ogún mi ti dàbí kinniun inú igbó sí mi,
ó ti sọ̀rọ̀ burúkú sí mi;
nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.
9Ṣé ogún mi ti dàbí ẹyẹ igún aláwọ̀ adíkálà ni?
Ṣé àwọn ẹyẹ igún ṣùrù bò ó ni?
Ẹ lọ pe gbogbo àwọn ẹranko igbó jọ,
ẹ kó wọn wá jẹun.
10Ọpọlọpọ àwọn darandaran ni wọ́n ti ba ọgbà àjàrà mi jẹ́,
wọ́n ti tẹ oko mi mọ́lẹ̀,
wọ́n sọ oko mi dáradára di aṣálẹ̀.
11Wọ́n sọ ọ́ di ahoro,
ilẹ̀ pàápàá ń ráhùn sí mi.
Wọ́n ti sọ gbogbo ilẹ̀ náà di ahoro,
ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún un.
12Àwọn apanirun ti dé sí gbogbo àwọn òkè inú pápá,
nítorí pé idà Ọlọrun ni ó ń run eniyan, jákèjádò ilẹ̀ náà;
ẹnikẹ́ni kò ní alaafia,
13Ọkà baali ni wọ́n gbìn, ṣugbọn ẹ̀gún ni wọ́n kórè.
Wọ́n ṣe làálàá, ṣugbọn wọn kò jèrè kankan.
Ojú yóo tì wọ́n nígbà ìkórè,
nítorí ibinu gbígbóná OLUWA.”
Ìlérí OLUWA fún Àwọn Aládùúgbò Israẹli
14Ohun tí OLUWA sọ nípa gbogbo àwọn aládùúgbò burúkú mi nìyí, àwọn tí wọn ń jí bù lára ilẹ̀ tí mo fún Israẹli, àwọn eniyan mi. Ó ní, “N óo kó wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn; n óo sì kó àwọn ọmọ Juda kúrò láàrin wọn. 15Lẹ́yìn tí mo bá kó wọn kúrò tán, n óo pada ṣàánú wọn, n óo dá olukuluku pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀. 16Nígbà tí ó bá yá, bí wọ́n bá fi tọkàntọkàn kọ́ àṣà àwọn eniyan mi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ mi búra, tí wọn ń wí pé, ‘Bí OLUWA Ọlọrun ti wà láàyè’, bí àwọn náà ṣe kọ́ àwọn eniyan mi láti máa fi orúkọ Baali búra, n óo fi ìdí wọn múlẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi. 17Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣe àìgbọràn, n óo yọ ọ́ kúrò patapata, n óo sì pa á run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Currently Selected:

JEREMAYA 12: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

Video for JEREMAYA 12