ÀWỌN ADÁJỌ́ 5
5
Orin Debora ati Baraki
1Debora ati Baraki ọmọ Abinoamu bá kọrin ní ọjọ́ náà pé:
2Ẹ fi ìyìn fún OLUWA,
nítorí pé, àwọn olórí ni wọ́n ṣiwaju ní Israẹli,
àwọn eniyan sì fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀.
3Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọba;
ẹ tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ìjòyè;
OLUWA ni n óo kọrin sí,
n óo kọrin dídùn sí OLUWA, Ọlọrun Israẹli.
4OLUWA, nígbà tí o jáde lọ láti òkè Seiri,
nígbà tí o jáde lọ láti agbègbè Edomu,
ilẹ̀ mì tìtì,
omi bẹ̀rẹ̀ sí bọ́,
ọ̀wààrà òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀.
5Àwọn òkè mì tìtì níwájú rẹ, OLUWA,#Eks 19:18
àní, ní òkè Sinai níwájú OLUWA, Ọlọrun Israẹli.
6Ní ìgbà ayé Ṣamgari, ọmọ Anati,
ati nígbà ayé Jaeli, ọ̀wọ́ èrò kò rin ilẹ̀ yìí mọ́,
àwọn arìnrìnàjò sì ń gba ọ̀nà kọ̀rọ̀.
7Gbogbo ìlú dá wáí ní Israẹli, ó dá,
gbogbo ìlú di àkọ̀tì,
títí tí ìwọ Debora fi dìde,
bí ìyá, ní Israẹli.
8Ní gbogbo ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli dá oriṣa titun,
ogun bo gbogbo ẹnubodè.
Ninu bí ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli,
ǹjẹ́ a rí ẹnikẹ́ni tí ó ní apata tabi ọ̀kọ̀?
9Ọkàn mi lọ sọ́dọ̀ àwọn balogun Israẹli,
tí wọ́n fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀ láàrin àwọn eniyan.
Ẹ fi ìyìn fún OLUWA.
10Ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ,
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jókòó lórí ẹní olówó iyebíye,
ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ rìn.
11Ẹ tẹ́tí sí ohùn àwọn akọrin lẹ́bàá odò,
ibẹ̀ ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun OLUWA,
ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun àwọn eniyan rẹ̀ ní Israẹli.
Àwọn eniyan OLUWA sì yan jáde láti ẹnubodè ìlú wọn.
12Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀! Debora!
Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀, kí o dárin!
Dìde, Baraki, máa kó àwọn tí o kó lógun lọ,
ìwọ ọmọ Abinoamu!
13Àwọn akikanju yòókù bẹ̀rẹ̀ sí yan bọ̀,
àwọn eniyan OLUWA náà sì ń wọ́ bọ̀,
láti gbógun ti alágbára.
14Wọ́n gbéra láti Efuraimu lọ sí àfonífojì náà,
wọ́n tẹ̀lé ọ, ìwọ Bẹnjamini pẹlu àwọn eniyan rẹ.
Àwọn ọ̀gágun wá láti Makiri,
àwọn olórí ogun sì wá láti Sebuluni.
15Àwọn ìjòyè Isakari náà bá Debora wá,
àwọn ọmọ Isakari jẹ́ olóòótọ́ sí Baraki,
wọ́n sì dà tẹ̀lé e lẹ́yìn lọ sí àfonífojì.
Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,
ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.
16Kí ló dé tí o fi dúró lẹ́yìn láàrin àwọn agbo aguntan?
Tí o fi ń gbọ́ bí àwọn olùṣọ́-aguntan ti ń fọn fèrè fún àwọn aguntan wọn.
Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,
ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.
17Àwọn ará Gileadi dúró ní ìlà oòrùn odò Jọdani,
kí ló dé tí ẹ̀yà Dani fi dúró ní ìdí ọkọ̀ ojú omi?
Àwọn ẹ̀yà Aṣeri jókòó létí òkun,
wọ́n wà ní ẹsẹ̀ odò.
18Àwọn ọmọ Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu dójú ikú,
bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ọmọ Nafutali,
wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wéwu ninu pápá, lójú ogun.
19“Ní Taanaki lẹ́bàá odò Megido
àwọn ọba wá, wọ́n jagun,
wọ́n bá àwọn ọba Kenaani jagun,
ṣugbọn wọn kò rí ìkógun fadaka kó.
20Láti ojú ọ̀run ni àwọn ìràwọ̀ ti ń jagun,
àní láti ààyè wọn lójú ọ̀nà wọn,
ni wọ́n ti bá Sisera jà.
21Odò Kiṣoni kó wọn lọ,
odò Kiṣoni, tí ó kún àkúnya.
Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, máa fi agbára yan lọ.
22Àwọn ẹṣin sáré dé, pẹlu ariwo pátákò ẹsẹ̀ wọn,
wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹsẹ̀ kilẹ̀.”
23Angẹli OLUWA ní, “Ìlú ègún ni ìlú Merosi,
ẹni ègún burúkú sì ni àwọn olùgbé rẹ̀,
nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò wá ran OLUWA lọ́wọ́;
wọn kò ran OLUWA lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn alágbára.”
24Ẹni ibukun jùlọ ni Jaeli láàrin àwọn obinrin,
Jaeli, aya Heberi, ọmọ Keni,
ẹni ibukun jùlọ láàrin àwọn obinrin tí ń gbé inú àgọ́.
25Omi ni Sisera bèèrè, wàrà ni Jaeli fún un,
àwo tí wọ́n fi ń gbé oúnjẹ fún ọba
ni ó fi gbé e fún un mu.
26Ó na ọwọ́ mú èèkàn àgọ́,
ó na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó he òòlù àwọn alágbẹ̀dẹ,
ó kan Sisera mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo;
ó fọ́ ọ lórí,
ó lù ú ní ẹ̀bá etí,
ó sì fọ́ yángá-yángá.
27Sisera wó, ó ṣubú lulẹ̀,
ó nà gbalaja lẹ́sẹ̀ Jaeli,
ó wó lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú lulẹ̀.
Ibi tí ó wó sí, náà ni ó sì kú sí.
28Ìyá Sisera ń yọjú láti ojú fèrèsé,
ó bẹ̀rẹ̀ sí wo ọ̀nà láti ibi ihò fèrèsé.
Ó ní, “Kí ló dé tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó dé?
Kí ló dé tí ó fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí á tó gbúròó ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin
tí wọ́n ń wọ́ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀?”
29Àwọn ọlọ́gbọ́n jùlọ ninu àwọn obinrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ dá a lóhùn,
òun náà sì ń wí fún ara rẹ̀ pé,
30“Ṣebí ìkógun ni wọ́n ń wá, tí wọ́n sì ń pín?
Obinrin kan tabi meji fún ọkunrin kọ̀ọ̀kan,
ìkógun àwọn aṣọ aláró fún Sisera,
ìkógun àwọn aṣọ aláró tí wọ́n dárà sí lára,
aṣọ ìborùn aláró meji tí wọ́n dárà sí lára fún èmi náà?”
31Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ṣègbé, OLUWA;
ṣugbọn bí oòrùn ti máa ń fi agbára rẹ̀ ràn,
bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa tàn.
Ilẹ̀ náà sì wà ní alaafia fún ogoji ọdún.
Currently Selected:
ÀWỌN ADÁJỌ́ 5: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010