YouVersion Logo
Search Icon

AISAYA 8

8
Ọmọ Aisaya jẹ́ Àmì fún Àwọn Eniyan
1Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún mi pé, “Mú ìwé kan tí ó fẹ̀, kí o kọ Maheriṣalali-haṣi-basi sí i lórí gàdàgbà gàdàgbà.”#8:1 Ìtumọ̀ Maheriṣalali-haṣi-basi ni ìkógun pàjáwìrì. 2Mo bá pe Alufaa Uraya ati Sakaraya, ọmọ Jebẹrẹkaya, kí wọn wá ṣe ẹlẹ́rìí mi nítorí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. 3Nígbà tí mo bá iyawo mi, tí òun náà jẹ́ wolii lò pọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin. OLUWA bá sọ fún mi pé kí n sọ ọmọ náà ní Maheriṣalali-haṣi-basi. 4Nítorí kí ọmọ náà tó mọ bí a tí ń pe ‘Baba mi’ tabi ‘Mama mi’, wọn óo ti kó àwọn nǹkan alumọni Damasku ati ìkógun Samaria lọ sí Asiria.
Ọba Asiria ń Bọ̀ Wá
5OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀ ó ní, 6“Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi kọ omi Ṣiloa tí ń ṣàn wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ sílẹ̀, wọ́n wá ń gbọ̀n jìnnìjìnnì níwájú Resini ati ọmọ Remalaya, 7nítorí náà, ẹ wò ó, OLUWA yóo gbé ọba Asiria ati gbogbo ògo rẹ̀ dìde wá bá wọn, yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí omi odò Yufurate, tí ó kún àkúnya, tí ó sì kọjá bèbè rẹ̀. 8Yóo ya wọ Juda, yóo sì bò ó mọ́lẹ̀ bí ó ti ń ṣàn kọjá lọ, títí yóo fi mù ún dé ọrùn. Yóo ya wọ inú ilẹ̀ rẹ̀ látòkè délẹ̀; yóo sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀. Kí Ọlọrun wà pẹlu wa.”
9Ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ kó ara yín jọ!
A óo fọ yín túútúú.
Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè.
Ẹ di ara yín ní àmùrè;
a óo fọ yín túútúú.
Ẹ di ara yín ní àmùrè,
a óo fọ yín túútúú.
10Bí ẹ gbìmọ̀ pọ̀ ìmọ̀ yín yóo di òfo.
Ohun yòówù tí ẹ lè sọ, àpérò yín yóo di asán.
Nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu wa.
OLUWA Kìlọ̀ fún Wolii
11Nítorí ọwọ́ agbára ni OLUWA fi lé mi lára, nígbà tí ó ń sọ èyí fún mi. Ó sì ti kìlọ̀ fún mi pé kí n má bá àwọn eniyan wọnyi rìn, ó ní, 12“Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ tí àwọn eniyan yìí ń dì. Bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bẹ̀rù ohun tí wọn ń bẹ̀rù. 13OLUWA àwọn ọmọ ogun nìkan ni kí o kà sí mímọ́, òun ni kí ẹ̀rù rẹ̀ máa bà ọ́. Òun nìkan ni kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa pá ọ láyà.#1 Pet 3:14-15 14Yóo di ibi-mímọ́ ati òkúta ìdìgbòlù, ati àpáta tí ó ń mú kí eniyan kọsẹ̀, fún ilẹ̀ Israẹli mejeeji. Yóo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fún àwọn ará Jerusalẹmu. 15Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo kọsẹ̀ níbẹ̀; wọn yóo ṣubú, wọn yóo sì fọ́ wẹ́wẹ́. Tàkúté yóo mú wọn, ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.”#1 Pet 2:8
Ìkìlọ̀ nípa Bíbá Òkú Sọ̀rọ̀
16Di ẹ̀rí náà, fi èdìdì di ẹ̀kọ́ náà láàrin àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi. 17N óo dúró de OLUWA ẹni tí ó fojú pamọ́ fún ilé Jakọbu, n óo sì ní ìrètí ninu rẹ̀.#Heb 2:13
18Ẹ wò ó! Èmi ati àwọn ọmọ tí OLUWA fún mi, a wà fún àmì ati ìyanu ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ń gbé orí òkè Sioni.#Heb 2:13
19Nígbà tí wọ́n bá wí fun yín pé kí ẹ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn àjẹ́ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀ tí wọn ń jẹ ẹnu wúyẹ́-wúyẹ́. Ṣé kò yẹ kí orílẹ̀-èdè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun wọn? Ṣé lọ́dọ̀ òkú ni ó ti yẹ kí alààyè ti máa wádìí ọ̀rọ̀?
20Ẹ lọ wádìí ninu ẹ̀kọ́ mímọ́ ati ẹ̀rí. Bí ẹnìkan bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí, kò sí òye ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.
Àkókò Ìṣòro
21Wọn yóo kọjá lọ lórí ilẹ̀ náà ninu ìnira ati ebi; nígbà tí ebi bá pa wọ́n, wọn yóo máa kanra, wọn óo gbé ojú wọn sókè, wọn óo sì gbé ọba ati Ọlọrun wọn ṣépè. 22Wọn óo bojú wo ilẹ̀, kìkì ìdààmú ati òkùnkùn ati ìṣúdudu ati ìnira ni wọn óo rí. A óo sì sọ wọ́n sinu òkùnkùn biribiri.

Currently Selected:

AISAYA 8: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in