YouVersion Logo
Search Icon

AISAYA 23

23
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire
1Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire nìyí:
Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọlọ́kọ̀ ojú omi ìlú Taṣiṣi;
nítorí pé Tire ti di ahoro,
láìsí ilé tabi èbúté!
Ní ilẹ̀ Kipru ni a ti fi eléyìí hàn wọ́n.
2Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,
ẹ̀yin oníṣòwò ará Sidoni;
àwọn iranṣẹ yín ti kọjá sí òdìkejì òkun,
3wọ́n gba orí alagbalúgbú omi kọjá lọ.
Èrè yín ni ọkà ìlú Sihori,
ìkórè etí odò Naili.
Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣòwò káàkiri àgbáyé.
4Ojú tì ọ́, ìwọ Sidoni
nítorí òkun ti fọhùn, agbami òkun ti sọ̀rọ̀, ó ní:
“N kò rọbí, bẹ́ẹ̀ ni n kò bímọ;
n kò tọ́ àwọn ọmọ dàgbà rí
kì báà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.”
5Nígbà tí ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Tire bá dé Ijipti
àwọn ará Ijipti yóo kérora.
6Ẹ kọjá lọ sí Taṣiṣi.
Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,
ẹ̀yin tí ó ń gbé etí òkun.
7Ṣé ìlú olókìkí yín náà nìyí,
tí a ti tẹ̀dó láti ìgbà àtijọ́!
Tí ó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,
tí ó ṣe àlejò lọ sibẹ!
8Ta ni ó gbìmọ̀ irú èyí sí Tire,
Ìlú tí ń fún àwọn ọba ìlú yòókù ládé?
Tí ó jẹ́ pé kìkì ìjòyè ni àwọn oníṣòwò rẹ̀;
gbogbo àwọn tí ń ta ọjà níbẹ̀ ni wọ́n jẹ́ ọlọ́lá ní gbogbo ayé.
9OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó pinnu láti ba gbogbo iyì ògo jẹ,
ati láti tẹ́ gbogbo àwọn ọlọ́lá ayé.
10Ẹ̀yin ará Taṣiṣi,
ẹ máa tàn ká orí ilẹ̀ yín títí ẹ ó fi kan odò Naili,
kò sí èbúté tí yóo da yín dúró mọ́.
11OLUWA ti na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun
Ó ti mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì.
Ó ti pàṣẹ nípa ilẹ̀ Kenaani
pé kí wọ́n pa gbogbo ibi ààbò rẹ̀ run.
12Ó ní, “Àríyá yín ti dópin,
ẹ̀yin ọmọ Sidoni tí à ń ni lára.
Ò báà dìde kí o lọ sí Kipru,
ara kò ní rọ̀ ọ́ níbẹ̀.”
13Ẹ wo ilẹ̀ àwọn ará Kalidea! Bí wọ́n ṣe wà bí aláìsí. Àwọn Asiria ti pinnu láti sọ Tire di ibùgbé àwọn ẹranko, wọ́n gbé àkàbà ogun ti odi rẹ̀. Wọ́n fogun kó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di ahoro.
14Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi, nítorí àwọn ilé ìṣọ́ yín tí ó lágbára ti wó.
15Nígbà, tó bá yá, Tire yóo di ìgbàgbé fún aadọrin ọdún gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ ọba kan; lẹ́yìn aadọrin ọdún ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Tire yóo dàbí orin kan tí àwọn aṣẹ́wó máa ń kọ pé:
16“Mú hapu, kí o máa káàkiri ààrin ìlú,
ìwọ aṣẹ́wó, ẹni ìgbàgbé.
Máa kọ orin dídùn ní oríṣìíríṣìí,
kí á lè ranti rẹ.”
17Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, OLUWA yóo ranti Tire. Yóo pada sídìí òwò aṣẹ́wó rẹ̀, yóo sì máa bá gbogbo ìjọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe òwò àgbèrè. 18Yóo ya ọjà tí ó ń tà ati èrè tí ó bá jẹ sọ́tọ̀ fún OLUWA, kò ní máa to èrè rẹ̀ jọ, tabi kí ó máa kó o pamọ́; ṣugbọn yóo máa lò wọ́n láti pèsè oúnjẹ ati aṣọ fún àwọn tí ó bá ń sin OLUWA.#Isi 26:1–28:19; Joẹl 3:4-8; Amos 1:9-10; Sek 9:1-4 Mat 11:21-22; Luk 10:13-14

Currently Selected:

AISAYA 23: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in