YouVersion Logo
Search Icon

HOSIA 10

10
1Àwọn ọmọ Israẹli dàbí àjàrà dáradára tí ń so èso pupọ. Bí èso rẹ̀ tí ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni pẹpẹ oriṣa wọn ń pọ̀ sí i. Bí àwọn ìlú wọn tí ń dára sí i ni àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn náà ń dára sí i. 2Èké ni wọ́n, nítorí náà wọn óo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, OLUWA yóo wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, yóo sì fọ́ àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn.
3Wọn óo máa wí nisinsinyii pé, “A kò ní ọba, nítorí pé a kò bẹ̀rù OLUWA; kí ni ọba kan fẹ́ ṣe fún wa?” 4Wọ́n ń fọ́nnu lásán; wọ́n ń fi ìbúra asán dá majẹmu; nítorí náà ni ìdájọ́ ṣe dìde sí wọn bíi koríko olóró, ní poro oko.
5Àwọn ará Samaria wárìrì fún ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, oriṣa ìlú Betafeni. Àwọn eniyan ibẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, àwọn babalóòṣà rẹ̀ yóo pohùnréré ẹkún lé e lórí, nítorí ògo rẹ̀ tí ó ti fò lọ. 6Dájúdájú, a óo gbé ère oriṣa náà lọ sí Asiria, a óo fi ṣe owó ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba ńlá ibẹ̀. Ojú yóo ti Efuraimu, ojú yóo sì ti Israẹli nítorí ère oriṣa rẹ̀. 7Ọba Samaria yóo parun bí ẹ̀ẹ́rún igi tí ó léfòó lórí omi. 8A óo pa ibi pẹpẹ ìrúbọ Afeni, tíí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli run; ẹ̀gún ati òṣùṣú yóo hù jáde lórí àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóo sì sọ fún àwọn òkè gíga pé kí wọ́n bo àwọn mọ́lẹ̀, wọn óo sì sọ fún àwọn òkè kéékèèké pé kí wọ́n wó lu àwọn.#Luk 23:30; Ifi 6:16
OLUWA Kéde Ìdájọ́ lórí Israẹli
9Láti ìgbà Gibea ni Israẹli ti ń dẹ́ṣẹ̀; sibẹ wọn kò tíì jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀. Ṣé ogun kò ní pa wọ́n ní Gibea?#A. Ada 19:1-30 10N óo dojú kọ àwọn tí ń ṣe ségesège n óo jẹ wọ́n níyà. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ láti kojú wọn, nígbà tí wọ́n bá ń jìyà fún ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
11Efuraimu dàbí ọmọ mààlúù tí a ti fi iṣẹ́ ṣíṣe kọ́, tí ó sì fẹ́ràn láti máa pa ọkà, mo fi ọrùn rẹ̀ tí ó lẹ́wà sílẹ̀; ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbé àjàgà bọ̀ ọ́ lọ́rùn, ó di dandan kí Juda kọ ilẹ̀, kí Israẹli sì máa ro oko fún ara rẹ̀. 12Ẹ gbin òdodo fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ẹ lọ dá oko sí ilẹ̀ tí ẹ ti kọ̀ sílẹ̀, nítorí ó tó àkókò láti wá OLUWA, kí ó lè wá rọ ìgbàlà le yín lórí bí òjò.#Jer 4:3 13Ẹ ti gbin ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti ká aiṣododo, ẹ ti jẹ èso ẹ̀tàn.
“Nítorí pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun ati ọpọlọpọ ọmọ ogun yín, 14nítorí náà, ogun yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan yín, gbogbo ibi ààbò yín ni yóo parun. Bí Ṣalimani ti pa Betabeli run, ní ọjọ́ ogun, ní ọjọ́ tí wọ́n pa ìyá tòun tọmọ; 15bẹ́ẹ̀ ni a óo ṣe si yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí ìwà burúkú yín. Bí ogun bá tí ń bẹ̀rẹ̀ ni a óo ti pa ọba Israẹli run.”

Currently Selected:

HOSIA 10: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in