YouVersion Logo
Search Icon

HEBERU 6

6
1Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa ẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ ti ìsìn igbagbọ tì, kí á tẹ̀síwájú láti kọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Kí á má tún máa fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ mọ́, ìpìlẹ̀ bí ẹ̀kọ́ nípa ìrònúpìwàdà kúrò ninu àwọn iṣẹ́ tí ó yọrí sí ikú, ẹ̀kọ́ nípa igbagbọ ninu Ọlọrun; 2ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi, ìgbé-ọwọ́-lé eniyan lórí, ajinde kúrò ninu òkú, ati ìdájọ́ ìkẹyìn. 3Ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú nípa kíkọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni a óo sì ṣe, bí Ọlọrun bá fẹ́.
4Nítorí àwọn tí a bá ti là lójú, tí wọ́n ti tọ́wò ninu ẹ̀bùn tí ó ti ọ̀run wá, àwọn tí wọ́n ti ní ìpín ninu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, 5tí wọ́n ti tọ́ ire tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ Ọlọrun wò, ati agbára ayé tí ó ń bọ̀, 6tí wọ́n bá wá yipada kúrò ninu ìsìn igbagbọ, kò sí ohun tí a lè ṣe tí wọ́n fi lè tún ronupiwada mọ́, nítorí wọ́n ti tún fi ọwọ́ ara wọn kan Ọmọ Ọlọrun mọ́ agbelebu, wọ́n sọ ikú rẹ̀ di nǹkan àwàdà.
7Nítorí nígbà tí ilẹ̀ bá ń mu omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó sì ń mú kí ohun ọ̀gbìn hù fún àwọn àgbẹ̀ tí ń roko níbẹ̀, ilẹ̀ náà ń gba ibukun Ọlọrun ni. 8Ṣugbọn bí ó bá ń hu ẹ̀gún ati igikígi, kò wúlò, kò sì ní pẹ́ tí Ọlọrun yóo fi fi í gégùn-ún. Ní ìkẹyìn, iná ni a óo dá sun ún.#Jẹn 3:17-18
9Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń sọ̀rọ̀ báyìí, sibẹ ó dá wa lójú nípa tiyín, ẹ̀yin àyànfẹ́, pé ipò yín dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ ní ohun tí ó yẹ fún ìgbàlà. 10Nítorí Ọlọrun kì í ṣe alaiṣootọ, tí yóo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ yín tí ẹ fihàn sí orúkọ rẹ̀, nígbà tí ẹ ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn onigbagbọ, bí ẹ ti tún ń ṣe nisinsinyii. 11Ìfẹ́ ọkàn wa ni pé kí olukuluku yín fi ìtara kan náà hàn, tí ẹ fi lè ní ẹ̀kún ìrètí yín títí dé òpin; 12kí ẹ má jẹ́ òpè, ṣugbọn kí ẹ fara wé àwọn tí wọ́n fi igbagbọ ati sùúrù jogún àwọn ìlérí Ọlọrun.
Ìlérí Ọlọrun Tí Ó Dájú
13Nítorí nígbà tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún Abrahamu, ara rẹ̀ ni ó fi búra nígbà tí kò sí ẹnìkan tí ó tóbi bíi rẹ̀ tí ìbá fi búra. 14Ó ní, “Ní ti ibukun, n óo bukun ọ. Ní ti kí eniyan pọ̀, n óo sọ ọ́ di pupọ.”#Jẹn 22:16-17 15Bẹ́ẹ̀ ni Abrahamu ṣe gba ìlérí náà pẹlu sùúrù. 16Ẹni tí ó bá juni lọ ni a fi í búra. Ọ̀rọ̀ tí eniyan bá sì ti búra lé lórí, kò sí àríyànjiyàn lórí rẹ̀ mọ́. 17Ní ọ̀nà kan náà, nígbà tí Ọlọrun fẹ́ fihàn gbangba fún àwọn ajogún ìlérí wí pé èrò òun kò yipada, ó ṣe ìlérí, ó sì fi ìbúra tì í. 18Èyí ni pé nípa ohun meji tí kò ṣe é yipada, tí Ọlọrun kò sì lè fi purọ́ ni àwa tí a sá di Ọlọrun fi lè ní ìwúrí pupọ láti di ìlérí tí ó wà níwájú wa mú. 19A di ìlérí náà mú. Ó dàbí ìdákọ̀ró fún ọkàn wa. Ìlérí yìí dájú, ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Ó ti wọ inú yàrá tí ó wà ninu, lẹ́yìn aṣọ ìkélé,#Lef 16:2 20níbi tí Jesu aṣiwaju wa ti wọ̀ lọ, tí ó di olórí alufaa títí lae gẹ́gẹ́ bíi Mẹlikisẹdẹki.#O. Daf 110:4

Currently Selected:

HEBERU 6: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in