HABAKUKU 1
1
1Ìran tí Ọlọrun fihan wolii Habakuku nìyí.
Ìráhùn Habakuku sí Ọlọrun
2OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí n óo máa ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́; tí o kò sì ní dá mi lóhùn? Tí n óo máa ké pé, “Wo ìwà ipá!” tí o kò sì ní gba olúwarẹ̀ sílẹ̀? 3Kí ló dé tí o fi ń jẹ́ kí n máa rí àwọn nǹkan tí kò tọ́, tí o jẹ́ kí n máa rí ìyọnu? Ìparun ati ìwà ipá wà níwájú mi, ìjà ati aáwọ̀ sì wà níbi gbogbo. 4Òfin kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́ òdodo. Àwọn ẹni ibi dòòyì ká olódodo, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ òdodo po.
Ìdáhùn Ọlọrun
5Ọlọrun ní: “Wo ààrin àwọn orílẹ̀-èdè yíká, O óo rí ohun ìjọjú yóo sì yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí mò ń ṣe nǹkan ìyanu kan ní àkókò rẹ, tí o kò ní gbàgbọ́ bí wọ́n bá sọ fún ọ.#A. Apo 13:41 6Wò ó! N óo gbé àwọn ará Kalidea dìde, orílẹ̀-èdè tí ó yára, tí kò sì ní àánú; àwọn tí wọ́n la ìbú ayé já, tí wọn ń gba ilẹ̀ onílẹ̀ káàkiri.#2A. Ọba 24:2 7Ìrísí wọn bani lẹ́rù; wọ́n ń fi ọlá ńlá wọn ṣe ìdájọ́ bí ó ti wù wọ́n.
8“Àwọn ẹṣin wọn yára ju àmọ̀tẹ́kùn lọ, wọ́n burú ju ìkookò tí ebi ń pa ní àṣáálẹ́ lọ. Pẹlu ìgbéraga ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn máa ń gun ẹṣin wọn lọ. Dájúdájú, ọ̀nà jíjìn ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ti ń wá; wọn a fò, bí idì tí ń sáré sí oúnjẹ.
9“Tìjàtìjà ni gbogbo wọn máa ń rìn, ìpayà á bá gbogbo eniyan bí wọ́n bá ti ń súnmọ́ tòsí. Wọn a kó eniyan ní ìgbèkùn, bí ẹni kó yanrìn nílẹ̀. 10Wọn a máa fi àwọn ọba ṣe ẹlẹ́yà, wọn a sì sọ àwọn ìjòyè di àmúṣèranwò. Wọn a máa fi àwọn ìlú olódi ṣe ẹlẹ́yà, nítorí òkítì ni wọ́n mọ sí ara odi wọn, wọn a sì gbà wọ́n. 11Wọn a fẹ́ wá bí ìjì, wọn a sì tún fẹ́ lọ, àwọn olubi eniyan, tí agbára wọn jẹ́ ọlọrun wọn.”
Habakuku tún Ráhùn sí OLUWA
12OLUWA, ṣebí láti ayérayé ni o ti wà? Ọlọrun mi, Ẹni Mímọ́ mi, a kò ní kú. OLUWA, ìwọ ni o yan àwọn ará Babiloni gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́. Ìwọ Àpáta, ni o gbé wọn kalẹ̀ bíi pàṣán, láti jẹ wá níyà. 13Mímọ́ ni ojú rẹ, o kò lè wo ibi o kò lè gba ohun tí kò tọ́. Kí ló wá dé tí o fi ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀, tí o sì dákẹ́, tí ò ń wo àwọn ẹni ibi níran tí wọn ń run àwọn tí wọ́n ṣe olódodo jù wọ́n lọ.
14Nítorí o ti jẹ́ kí ọmọ eniyan dàbí ẹja inú òkun, ati bí àwọn kòkòrò tí wọn ń rìn nílẹ̀, tí wọn kò ní olórí. 15Ọ̀tá fi ìwọ̀ fa gbogbo wọn sókè, ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ kó wọn jáde. Ó kó wọn papọ̀ sinu àwọ̀n rẹ̀, Nítorí náà ó ń yọ̀, inú rẹ̀ sì dùn. 16Nítorí náà a máa bọ àwọ̀n rẹ̀. A sì máa fi turari rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀ ńlá; nítorí a máa rò lọ́kàn rẹ̀ pé, àwọ̀n òun ni ó ń jẹ́ kí òun gbádùn ayé tí òun sì fi ń rí oúnjẹ aládùn jẹ.
17Ṣé gbogbo ìgbà ni àwọn eniyan yóo máa bọ́ sinu àwọ̀n rẹ̀ ni? Ṣé títí lae ni yóo sì máa pa àwọn orílẹ̀-èdè run láìláàánú?
Currently Selected:
HABAKUKU 1: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010