YouVersion Logo
Search Icon

ISIKIẸLI 10

10
Ògo OLUWA Kúrò Ninu Tẹmpili Náà
1Lẹ́yìn náà, mo wo orí àwọn Kerubu, mo rí kinní kan róbótó róbótó, wọ́n dàbí òkúta safire, ìrísí wọn dàbí ìtẹ́. 2Ọlọrun bá sọ fún ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà pé, “Bọ́ sí ààrin àwọn àgbá tí wọn ń yí, tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn Kerubu. Bu ẹ̀yinná tí ó wà láàrin wọn kún ọwọ́ rẹ, kí o sì fọ́n ọn sórí ìlú yìí káàkiri.”#Isi 1:26, Ifi 4:2 #Ifi 8:5
Mo bá rí i tí ó wọlé lọ. 3Ìhà gúsù ilé náà ni àwọn Kerubu dúró sí nígbà tí ọkunrin náà wọlé, ìkùukùu sì bo àgbàlá ààrin ilé náà. 4Ìfarahàn ògo OLUWA gbéra kúrò lórí àwọn Kerubu, ó lọ dúró sí àbáwọlé. Ìkùukùu kún gbogbo inú ilé náà, ìmọ́lẹ̀ ògo OLUWA sì kún gbogbo inú àgbàlá. 5Ariwo ìyẹ́ àwọn Kerubu náà dé àgbàlá òde. Ó dàbí ìgbà tí Ọlọrun Olodumare bá ń sọ̀rọ̀.
6Nígbà tí OLUWA pàṣẹ fún ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà pé kí ó mú iná láàrin àwọn àgbá tí ń yí, tí ó wà láàrin àwọn Kerubu, ọkunrin náà wọlé, ó lọ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbá náà. 7Ọ̀kan lára àwọn Kerubu náà na ọwọ́ sí inú iná tí ó wà láàrin wọn, ó bù ú sí ọwọ́ ọkunrin aláṣọ funfun náà. Ọkunrin náà gbà á, ó sì jáde.
8Ó dàbí ẹni pé àwọn Kerubu náà ní ọwọ́ bíi ti eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn. 9Mo wòye, mo sì rí i pé àgbá mẹrin ni ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Kerubu náà: àgbá kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Kerubu kọ̀ọ̀kan. Àwọn kẹ̀kẹ́ náà ń dán yinrinyinrin bí òkúta Kirisolite. 10Àwọn mẹrẹẹrin rí bákan náà, ó sì dàbí ìgbà tí àwọn àgbá náà wọnú ara wọn. 11Bí wọn tí ń lọ, ibikíbi tí ó bá wu àwọn Kerubu náà ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin tí wọ́n kọjú sí ni wọ́n lè lọ láì jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada, nítorí pé ibikíbi tí èyí tí ó wà níwájú bá kọjú sí ni àwọn yòókù máa ń lọ. 12Gbogbo ara wọn àtẹ̀yìn wọn, àtọwọ́, àtìyẹ́ ati gbogbo ẹ̀gbẹ́ kẹ̀kẹ́ wọn kún fún ojú. 13Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn àgbá náà ní àgbá tí ń sáré yí.#Isi 1:15-21 #Ifi 4:8
14Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní iwájú mẹrin mẹrin. Iwájú kinni jẹ́ iwájú Kerubu, ekeji jẹ́ iwájú eniyan, ẹkẹta jẹ́ iwájú kinniun, ẹkẹrin sì jẹ́ iwájú ẹyẹ idì. 15Àwọn Kerubu náà bá gbéra nílẹ̀, àwọn ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí ní etí odò Kebari. 16Bí wọn tí ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbá náà ń lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Bí àwọn Kerubu náà bá fẹ́ fò, tí wọ́n bá na ìyẹ́ apá wọn, àwọn àgbá náà kìí kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. 17Bí wọn bá dúró, àwọn náà á dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn náà á gbéra, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà ninu wọn.#Isi 1:0; Ifi 4:7
18Ìtànṣán ògo OLUWA jáde kúrò ní àbáwọlé, ó sì dúró sí orí àwọn Kerubu náà. 19Àwọn Kerubu bá na ìyẹ́ apá wọn, wọ́n gbéra nílẹ̀ lójú mi, bí wọ́n ti ń lọ, àwọn àgbá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn. 20Àwọn wọnyi ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọrun Israẹli ní etí odò Kebari. Mo sì mọ̀ pé Kerubu ni wọ́n.
21Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní iwájú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin, wọ́n sì ní ọwọ́ bí ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn. 22Bí iwájú àwọn tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari ti rí gan-an ni iwájú wọn rí. Olukuluku ń rìn lọ siwaju tààrà.

Currently Selected:

ISIKIẸLI 10: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in