EFESU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Pataki ohun tí Paulu sọ̀rọ̀ bá ninu ìwé yìí ni ètò tí Ọlọrun ṣe láti kó gbogbo ẹ̀dá jọ pọ̀, ati láti fihàn pé Kristi ni orí ohun gbogbo: ìbáà jẹ́ láyé ni tabi lọ́run (1:10). Ìwé yìí tún jẹ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo eniyan Ọlọrun láti máa gbé irú ìgbé-ayé tí yóo jẹ́ kí àwọn eniyan rí ìtumọ̀ ètò Ọlọrun fún ìṣọ̀kan gbogbo eniyan nípa pé kí á ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi.
Ninu apá kinni Ìwé Efesu, Paulu ṣe àlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa ìṣọ̀kan, tíí ṣe kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ninu àlàyé rẹ̀, ó mẹ́nuba bí Ọlọrun Baba ti yan àwọn eniyan rẹ̀, ati bí ó ṣe dáríjì wọ́n, bí ó ṣe dá wọn nídè kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀, ati bí Ọlọrun ṣe rán Ẹ̀mí Mímọ́ láti fún wa ní ìdánilójú pé ìlérí ńlá Ọlọrun tó gbẹ́kẹ̀lé. Ninu apá keji ìwé yìí Paulu rọ gbogbo àwọn tí wọ́n bá ka ìwé yìí láti gbé irú ìgbé-ayé tí yóo jẹ́ kí ìṣọ̀kan wọn kúrò ní àfẹnujẹ́ ninu ìgbépọ̀ wọn.
Oríṣìíríṣìí èdè àpèjúwe ni Paulu lò láti fihàn pé ọ̀kan náà ni gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí wọ́n bá ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi. Ìjọ dàbí ara eniyan: Kristi ni ó dàbí orí. Ó tún fi ìjọ wé ilé, Kristi sì jẹ́ òkúta igun ilé. Ohun tí a tún lè fi ìjọ wé ni iyawo, Kristi ni ọkọ. Èdè tí ẹni tí ó kọ ìwé yìí lò bẹ̀rẹ̀ sí dùn mọ́ eniyan létí sí i bí ìrònú lórí oore-ọ̀fẹ́ ninu Kristi ti bẹ̀rẹ̀ sí gba ọkàn rẹ̀ sí i. A rí gbogbo nǹkan ninu ìfẹ́ Kristi ati ìrúbọ rẹ̀, ìdáríjì rẹ̀, oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ati jíjẹ́ mímọ́ rẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-2
Kristi ati ìjọ 1:3–3:21
Ìgbé-ayé titun ninu Kristi 4:1–6:20
Ọ̀rọ̀ ìparí 6:21-24
Currently Selected:
EFESU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010