DIUTARONOMI 23
23
Yíyọ Orúkọ Eniyan kúrò ninu Orúkọ Àwọn Eniyan OLUWA
1“Ọkunrin tí wọ́n bá tẹ̀ lọ́dàá, tabi tí wọ́n bá gé nǹkan ọkunrin rẹ̀, kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ.
2“Ọmọ àlè kankan kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ, arọmọdọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹwaa kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ.
3“Ará Amoni ati Moabu kankan kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ, arọmọdọmọ wọn títí dé ìran kẹwaa kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ; 4nítorí pé, nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, wọn kò gbé oúnjẹ ati omi pàdé yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, Balaamu ọmọ Beori ará Petori, ní Mesopotamia, ni wọ́n bẹ̀ pé kí ó wá gbé yín ṣépè.#Nọm 22:1-6 5Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín kò fetí sí ti Balaamu, ó yí èpè náà sí ìre fun yín nítorí pé ó fẹ́ràn yín.#Nọm 23:7-24:9 #Neh 13:1-2. 6Ẹ kò gbọdọ̀ ro ire kàn wọ́n tabi kí ẹ wá ìtẹ̀síwájú wọn títí lae.
7“Ẹ kò gbọdọ̀ kórìíra àwọn ọmọ Edomu, nítorí pé arakunrin yín ni wọ́n. Ẹ kò gbọdọ̀ kórìíra àwọn ará Ijipti nítorí pé ẹ ti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ wọn rí. 8Bẹ̀rẹ̀ láti ìran kẹta wọn, wọ́n lè bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ.
Jíjẹ́ Kí Àgọ́ Àwọn Ọmọ-ogun Wà ní Mímọ́
9“Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jagun, tí ẹ bá sì wà ninu àgọ́, ẹ níláti yẹra fún ohunkohun tíí ṣe ibi. 10Bí ọkunrin kan bá wà ninu yín tí ó di aláìmọ́ nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i láàrin òru, kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kúrò ninu àgọ́. Kò gbọdọ̀ wọ inú àgọ́ wá mọ́. 11Ṣugbọn nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́, kí ó wẹ̀. Nígbà tí oòrùn bá sì wọ̀, ó lè wọ inú àgọ́ wá.
12“Ẹ gbọdọ̀ ní ibìkan lẹ́yìn àgọ́ tí ẹ óo máa yàgbẹ́ sí. 13Kí olukuluku yín ní ọ̀pá kan, tí yóo máa dì mọ́ ara ohun ìjà rẹ̀, tí ó lè fi gbẹ́lẹ̀ nígbà tí ó bá fẹ́ yàgbẹ́; nígbà tí ó bá sì yàgbẹ́ tán, ọ̀pá yìí ni yóo fi wa erùpẹ̀ bò ó mọ́lẹ̀. 14Nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín wà pẹlu yín ninu àgọ́ láti gbà yín là, ati láti jẹ́ kí ọwọ́ yín tẹ àwọn ọ̀tá yín. Nítorí náà, àgọ́ yín níláti jẹ́ mímọ́, kí OLUWA má baà rí ohunkohun tí ó jẹ́ àìmọ́ láàrin yín, kí ó sì yipada kúrò lọ́dọ̀ yín.
Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn
15“Bí ẹrú kan bá sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, tí ó bá tọ̀ yín wá, ẹ kò gbọdọ̀ lé e pada sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. 16Ẹ jẹ́ kí ó máa bá yín gbé, kí ó wà láàrin yín ninu èyíkéyìí tí ó bá yàn ninu àwọn ìlú yín. Ibi tí ó bá wù ú ni ó lè gbé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ni ín lára.
17“Ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan Israẹli, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di alágbèrè ní ilé oriṣa kankan. 18Ọkunrin tabi obinrin kankan kò gbọdọ̀ mú owó tí ó bá gbà ní ibi àgbèrè ṣíṣe wá sinu ilé OLUWA láti san ẹ̀jẹ́kẹ́jẹ̀ẹ́ tí ó bá jẹ́, nítorí pé, àgbèrè ṣíṣe jẹ́ ohun ìríra níwájú OLUWA Ọlọrun yín.#Lef 19:29
19“Tí ẹ̀yin ọmọ Israẹli bá yá ara yín lówó, tabi oúnjẹ tabi ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé lórí rẹ̀. 20Bí ẹ bá yá àlejò ní nǹkan, ẹ lè gba èlé, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ yá arakunrin yín ní ohunkohun kí ẹ sì gba èlé, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà.#Eks 22:25; Lef 25:36-37; Diut 15:7-11.
21“Nígbà tí ẹ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbọdọ̀ má san ẹ̀jẹ́ náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ yín, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn bí ẹ kò bá san án. 22Ṣugbọn tí ẹ kò bá jẹ́jẹ̀ẹ́ rárá, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. 23Níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá ti fínnúfẹ́dọ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́ ohunkohun fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ti fi ẹnu yín ṣèlérí, ẹ sì níláti rí i pé, ẹ mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ.#Nọm 30:1-16; Mat 5:33.
24“Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní ibi ọgbà àjàrà ẹlòmíràn, ẹ lè jẹ ìwọ̀nba èso àjàrà tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mú ẹyọkan lọ́wọ́ lọ. 25Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní oko ọkà ẹlòmíràn, tí wọn kò tíì kórè, ẹ lè fi ọwọ́ ya ìwọ̀nba tí ẹ lè jẹ, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ fi dòjé gé ọkà ọlọ́kà.
Currently Selected:
DIUTARONOMI 23: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010