SAMUẸLI KEJI 6
6
Wọ́n Gbé Àpótí Ẹ̀rí Wá sí Jerusalẹmu
(1Kron 13:1-14; 15:25–16:6,43)
1Dafidi tún pe gbogbo àwọn akikanju ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ; wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000). 2Ó kó wọn lọ sí Baala ní Juda láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun wá sí Jerusalẹmu. Orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni wọ́n fi ń pe àpótí ẹ̀rí náà, ìtẹ́ rẹ̀ sì wà lórí àwọn Kerubu tí ó wà lókè àpótí náà. 3Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí jáde kúrò ní ilé Abinadabu tí ó wà lórí òkè, wọ́n sì gbé e ka orí kẹ̀kẹ́ tuntun kan. Usa ati Ahio ọmọ Abinadabu sì ń ti kẹ̀kẹ́ náà; 4Ahio ni ó ṣáájú rẹ̀. 5Dafidi ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí jó níwájú OLUWA, wọ́n sì ń kọrin pẹlu gbogbo agbára wọn. Wọ́n ń lu àwọn ohun èlò orin olókùn tí wọ́n ń pè ní hapu, ati lire; ati ìlù, ati ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ati aro. #Eks 25:22 #1 Sam 7:1-2
6Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Nakoni, àwọn mààlúù tí ń fa kẹ̀kẹ́ tí àpótí ẹ̀rí wà lórí rẹ̀ kọsẹ̀, Usa bá yára di àpótí ẹ̀rí náà mú. 7Inú bí OLUWA sí Usa, OLUWA sì lù ú pa nítorí pé ó fi ọwọ́ kan àpótí ẹ̀rí náà. Usa kú sẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà. 8Inú bí Dafidi gidigidi nítorí pé OLUWA lu Usa pa. Láti ìgbà náà ni wọ́n ti ń pe ibẹ̀ ní Peresi Usa, títí di òní olónìí.
9Ẹ̀rù OLUWA ba Dafidi ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Báwo ni n óo ṣe gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA wá sọ́dọ̀ mi?” 10Ọkàn rẹ̀ bá yipada, ó pinnu pé òun kò ní gbé e lọ sí Jerusalẹmu, ìlú Dafidi mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gbé e lọ sí ilé Obedi Edomu, ará ìlú Gati. 11Àpótí ẹ̀rí OLUWA náà wà níbẹ̀ fún oṣù mẹta, OLUWA sì bukun Obedi Edomu ati ìdílé rẹ̀. #1Kron 26:4-5
12Wọ́n bá lọ sọ fún Dafidi pé, “OLUWA ti bukun Obedi Edomu, ati gbogbo ohun tí ó ní, nítorí pé àpótí ẹ̀rí OLUWA wà ní ilé rẹ̀.” Dafidi bá lọ gbé àpótí ẹ̀rí náà kúrò ní ilé rẹ̀ wá sí Jerusalẹmu, pẹlu àjọyọ̀ ńlá. 13Lẹ́yìn tí àwọn tí wọ́n ru àpótí ẹ̀rí náà ti gbé ìṣísẹ̀ mẹfa, Dafidi dá wọn dúró, ó sì fi akọ mààlúù kan ati ọmọ mààlúù àbọ́pa kan rúbọ sí OLUWA. 14Dafidi sán aṣọ mọ́dìí, ó sì ń jó pẹlu gbogbo agbára níwájú OLUWA. 15Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA wọ Jerusalẹmu, pẹlu ìhó ayọ̀ ati ìró fèrè.
16Bí wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí náà wọ inú ìlú Dafidi, Mikali ọmọ Saulu yọjú wo òde láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi ọba tí ó ń jó tí ó sì ń fò sókè níwájú OLUWA, Mikali sì kẹ́gàn rẹ̀ ninu ọkàn rẹ̀. 17Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí náà wọnú ìlú, wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀, ninu àgọ́ tí Dafidi ti kọ́ sílẹ̀ fún un. Dafidi sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. 18Nígbà tí ó rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan náà ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun. 19Ó sì pín oúnjẹ fún gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin. Ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìṣù àkàrà kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran kọ̀ọ̀kan, ati àkàrà tí wọ́n fi èso resini sí ninu. Lẹ́yìn náà, olukuluku lọ sí ilé.
20Nígbà tí wọ́n parí, Dafidi pada sí ilé láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀. Mikali, ọmọ Saulu, bá lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba Israẹli mà dárà lónìí! Ọba yán gbogbo aṣọ kúrò lára, bí aláìlóye eniyan níwájú àwọn iranṣẹbinrin àwọn iranṣẹ rẹ̀!” #1Kron 16:43
21Dafidi dá a lóhùn pé, “Ijó ni mò ń jó, níwájú OLUWA tí ó yàn mí dípò baba rẹ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, láti fi mí ṣe alákòóso Israẹli, àwọn eniyan OLUWA. N óo tún máa jó níwájú OLUWA. 22Kékeré ni èyí tí mo ṣe yìí, n óo máa ṣe jù bí mo ti ṣe yìí lọ. N kò ní jẹ́ nǹkankan lójú rẹ, ṣugbọn àwọn iranṣẹbinrin tí o sọ nípa wọn yìí, yóo bu ọlá fún mi.”
23Mikali, ọmọbinrin Saulu, kò sì bímọ títí ó fi kú.
Currently Selected:
SAMUẸLI KEJI 6: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010