ÀWỌN ỌBA KEJI 8
8
Obinrin Ará Ṣunemu náà Pada
1Eliṣa sọ fún obinrin ará Ṣunemu, ẹni tí Eliṣa jí ọmọ rẹ̀ tí ó kú pé, “OLUWA yóo rán ìyàn sí ilẹ̀ yìí fún ọdún meje, nítorí náà, kí ìwọ ati ẹbí rẹ lọ máa gbé ní ilẹ̀ mìíràn.” 2Obinrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Eliṣa, òun ati ẹbí rẹ̀ sì lọ ń gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ọdún meje.#2A. Ọba 4:8-37
3Lẹ́yìn ọdún keje, obinrin náà pada sí Israẹli, ó sì lọ sọ́dọ̀ ọba láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó dá ilé ati ilẹ̀ òun pada. 4Ó bá ọba tí ó ń bá Gehasi iranṣẹ Eliṣa sọ̀rọ̀; ọba fẹ́ mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Eliṣa. 5Bí Gehasi ti ń sọ fún ọba bí Eliṣa ṣe jí òkú dìde, ni obinrin tí Eliṣa jí òkú ọmọ rẹ̀ dìde wá sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba. Gehasi sọ fún ọba pé, “Olúwa mi, obinrin náà nìyí, ọmọkunrin rẹ̀ tí Eliṣa jí dìde náà sì nìyí.” 6Ọba bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà, ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún ọba. Ọba bá pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ kí ó fún obinrin náà ní gbogbo ohun tíí ṣe tirẹ̀ pẹlu gbogbo ohun tí wọ́n ti kórè ninu oko náà, láti ìgbà tí obinrin náà ti fi ìlú sílẹ̀ títí di ìgbà tí ó pada dé.
Eliṣa ati Benhadadi Ọba Siria
7Eliṣa lọ sí Damasku ní àkókò kan tí Benhadadi ọba Siria wà lórí àìsàn. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé Eliṣa wà ní Damasku, 8ọba sọ fún Hasaeli, ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, kí o sì lọ bá wolii náà, kí o sọ fún un pé kí ó bá mi bèèrè lọ́wọ́ OLUWA bóyá n óo yè ninu àìsàn yìí.” 9Hasaeli di ogoji ẹrù ràkúnmí tí ó kún fún oniruuru ohun rere tí ó wà ní Damasku, ó lọ bá Eliṣa. Nígbà tí Hasaeli pàdé rẹ̀, ó sọ pé, “Iranṣẹ rẹ, Benhadadi, ọba Siria, rán mi láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ bóyá òun óo yè ninu àìsàn òun.”
10Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé yóo kú, ṣugbọn lọ sọ fún un pé yóo yè.” 11Eliṣa tẹjú mọ́ Hasaeli títí ojú fi tì í. Eliṣa sì sọkún. 12Hasaeli bèèrè pé, “Kí ló dé tí o fi ń sunkún, oluwa mi?”
Eliṣa dáhùn pé, “Nítorí pé mo mọ oríṣìíríṣìí nǹkan burúkú tí o óo ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli: O óo jó ibi ààbò wọn, o óo fi idà pa àwọn ọmọkunrin wọn, o óo tú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn ká, o óo sì la inú àwọn aboyún wọn.”
13Hasaeli dáhùn pé, “Ta ni mí, tí n óo fi ṣe nǹkan tí ó lágbára tóbẹ́ẹ̀?”
Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé o óo jọba ní Siria.”#1A. Ọba 19:15
14Ó bá pada lọ sọ́dọ̀ Benhadadi, ó sì bèèrè ohun tí Eliṣa sọ lọ́wọ́ rẹ̀.
Hasaeli dáhùn pé, “O óo yè ninu àìsàn rẹ.” 15Ní ọjọ́ keji Hasaeli mú aṣọ tí ó nípọn, ó rì í bọ omi, ó sì fi bo ojú Benhadadi títí ó fi kú.
Hasaeli sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Jehoramu Ọba Juda
(2Kron 21:1-20)
16Ní ọdún karun-un tí Joramu ọmọ Ahabu jọba ní Israẹli, ni Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jọba ní ilẹ̀ Juda. 17Ẹni ọdún mejilelọgbọn ni, nígbà tí ó jọba, ó sì jọba fún ọdún mẹjọ. 18Ó tẹ̀ sí ọ̀nà àwọn ọba Israẹli gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu nítorí ọmọ Ahabu, ni iyawo rẹ̀, ó ṣe ibi níwájú OLUWA. 19Sibẹsibẹ OLUWA kò pa Juda run nítorí ó ti búra fún Dafidi iranṣẹ rẹ̀ pé ìran rẹ̀ yóo máa jọba ní ilẹ̀ Juda.#1A. Ọba 11:36
20Ní àkókò ìjọba Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì yan ọba fún ara wọn. 21Nítorí náà, Jehoramu kó gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí Sairi láti bá Edomu jagun. Níbẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun Edomu ti yí wọn ká. Ní òru, òun ati àwọn olórí ogun rẹ̀ kọlu àwọn ará Edomu tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n sì sá àsálà, ṣugbọn àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sá pada sí ilé wọn. 22Láti ìgbà náà ni Edomu ti di òmìnira kúrò lọ́wọ́ Juda. Ní àkókò kan náà ni ìlú Libina ṣọ̀tẹ̀ sí Juda.#Jẹn 27:40
23Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Jehoramu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. 24Jehoramu kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Ahasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Ahasaya Ọba Juda
(2Kron 22:1-6)
25Ní ọdún kejila tí Joramu ọmọ Ahabu ti jọba ní Israẹli ni Ahasaya, ọmọ Jehoramu, jọba ní ilẹ̀ Juda. 26Ẹni ọdún mejilelogun ni nígbà tí ó jọba ni Jerusalẹmu, ó sì jọba fún ọdún kan. Atalaya ni ìyá rẹ̀, ọmọ Omiri, ọba ilẹ̀ Israẹli. 27Ọ̀nà ìdílé Ahabu ọba ni Ahasaya tẹ̀ sí, ó sì ṣe burúkú níwájú OLUWA, bí ìdílé Ahabu ti ṣe; nítorí pé àna ló jẹ́ fún Ahabu.
28Ahasaya bá Joramu, ọba Israẹli lọ, wọ́n gbógun ti Hasaeli, ọba Siria, ní Ramoti Gileadi. Àwọn ọmọ ogun Siria ṣá ọba Joramu lọ́gbẹ́. 29Ó pada sí ìlú Jesireeli, ó lọ wo ọgbẹ́ náà sàn. Ahasaya, ọba Juda, ọmọ Jehoramu, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli.
Currently Selected:
ÀWỌN ỌBA KEJI 8: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010