YouVersion Logo
Search Icon

KRONIKA KEJI 4

4
Àwọn Ohun Èlò Inú Tẹmpili
(1A. Ọba 7:23-51)
1Solomoni ọba ṣe pẹpẹ idẹ kan tí ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½). 2Ó ṣe agbada omi kan tí ó fẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½), ó sì ga ní igbọnwọ marun-un (mita 2¼). Àyíká etí rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 13½). 3Gbogbo ẹ̀yìn agbada yìí ni ó ya àwòrán mààlúù sí ní ìlà meji meji yíká ìsàlẹ̀ etí rẹ̀. 4Agbada yìí wà lórí ère mààlúù mejila tí wọ́n kọjú síta: mẹta kọjú sí ìhà àríwá, mẹta kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹta kọjú sí ìhà gúsù, mẹta yòókù sì kọjú sí ìlà oòrùn. 5Agbada náà nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ dàbí etí ife omi ati bí òdòdó lílì. Agbada náà gbà tó ẹgbẹẹdogun ìwọ̀n bati omi. 6Ó ṣe abọ́ ńlá mẹ́wàá, ó gbé marun-un ka ẹ̀gbẹ́ gúsù, ó sì gbé marun-un yòókù ka ẹ̀gbẹ́ àríwá. Àwọn abọ́ wọnyi ni wọ́n fi ń bu omi láti fọ àwọn ohun tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Omi inú agbada náà sì ni àwọn alufaa máa ń lò láti fi wẹ̀. #Eks 27:1-2 #Eks 30:17-21
7Solomoni ṣe ọ̀pá fìtílà wúrà mẹ́wàá bí àpẹẹrẹ tí wọ́n fún un. Ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá. 8Ó ṣe tabili mẹ́wàá, ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá. Ó sì ṣe ọgọrun-un àwo kòtò wúrà.
9Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan fún àwọn alufaa, ati òmíràn tí ó tóbi, ó ṣe ìlẹ̀kùn sí wọn, ó sì yọ́ idẹ bo àwọn ìlẹ̀kùn náà. 10Ó gbé agbada omi kalẹ̀ sí apá gúsù ìhà ìlà oòrùn igun ilé náà. #Eks 25:31-46 #Eks 25:23-30
11Huramu mọ ìkòkò, ó rọ ọkọ́, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó ṣe sinu ilé Ọlọrun fún Solomoni ọba. 12Àwọn iṣẹ́ náà nìwọ̀nyí: Òpó meji, àwọn ọpọ́n meji tí wọ́n dàbí abọ́ tí wọ́n wà lórí àwọn òpó náà, nǹkankan tí ó dàbí ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dárà sára àwọn ọpọ́n tí ó wà lórí òpó náà, 13àwọn irinwo òdòdó idẹ tí wọ́n fi ṣe ọnà ní ìlà meji meji yí ọpọ́n orí àwọn òpó náà ká. 14Ó ṣe àwọn abọ́ ńlá ati ìjókòó wọn. 15Ó ṣe agbada omi kan ati ère mààlúù mejila sí abẹ́ rẹ̀. 16Ó mọ àwọn ìkòkò, ó rọ ọkọ́ ati àmúga tí wọ́n fi ń mú ẹran, ati gbogbo ohun èlò wọn. Idẹ dídán ni Huramu fi ṣe gbogbo wọn fún Solomoni ọba, fún lílò ninu ilé OLUWA.
17Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani tí ó jẹ́ ilẹ̀ amọ̀, láàrin Sukotu ati Sereda ni ọba ti ṣe wọ́n. 18Àwọn nǹkan tí Solomoni ṣe pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí a kò fi mọ ìwọ̀n idẹ tí ó lò.
19Solomoni ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ilé Ọlọrun: pẹpẹ wúrà, tabili fún burẹdi ìfihàn. 20Àwọn ọ̀pá ati fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe láti máa jò níwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ. 21Ó fi wúrà tí ó dára jùlọ ṣe àwọn òdòdó, àwọn fìtílà ati àwọn ẹ̀mú. 22Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ohun tí wọ́n fi ń tún òwú fìtílà ṣe ati àwọn àwo kòtò; àwọn àwo turari, ati àwọn àwo ìmúná. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn ìta tẹmpili, ati ìlẹ̀kùn síbi mímọ́ jùlọ, ati ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn tẹmpili náà.

Currently Selected:

KRONIKA KEJI 4: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy