YouVersion Logo
Search Icon

KRONIKA KEJI 21

21
1Jehoṣafati kú, wọ́n sin ín pẹlu àwọn baba rẹ̀ ninu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Jehoramu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Jehoramu, Ọba Juda
(2A. Ọba 8:17-24)
2Jehoramu ní arakunrin mẹfa, tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Jehoṣafati, orúkọ wọn ni, Asaraya, Jehieli, ati Sakaraya, Asaraya, Mikaeli ati Ṣefataya. 3Baba wọn fún wọn ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn: fadaka, wúrà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye, pẹlu àwọn ìlú olódi ní Juda. Ṣugbọn Jehoramu ni ó fi ìjọba lé lọ́wọ́, nítorí pé òun ni àkọ́bí rẹ̀. 4Nígbà tí ó jọba tán, tí ó sì ti fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, ó fi idà pa gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ati díẹ̀ ninu àwọn olóyè ní Israẹli.
5Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún mejilelọgbọn nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹjọ ní Jerusalẹmu. 6Ó tẹ̀ sí ọ̀nà burúkú tí àwọn ọba Israẹli rìn, ó ṣe bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí pé ọmọ Ahabu ni iyawo rẹ̀. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. 7Sibẹsibẹ OLUWA kò pa ìdílé Dafidi run nítorí majẹmu tí ó ti bá Dafidi dá, ati ìlérí tí ó ti ṣe pé ọmọ rẹ̀ ni yóo máa wà lórí oyè títí lae.#1A. Ọba 11:36
8Ní àkókò ìjọba Jehoramu ni Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì yan ọba fún ara wọn.#Jẹn 27:40
9Nítorí náà Jehoramu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ lọ gbógun tì wọ́n. Ní òru, Jehoramu ati ogun rẹ̀ dìde, wọ́n fọ́ ogun Edomu tí ó yí wọn ká tàwọn ti kẹ̀kẹ́ ogun wọn, ati àwọn tí ń wà wọ́n. 10Láti ìgbà náà ni Edomu ti ń bá Juda ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí. Ní àkókò kan náà ni Libina ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, ó sì gba òmìnira nítorí pé Jehoramu ti fi ọ̀nà OLUWA àwọn baba rẹ̀ sílẹ̀. 11Ó tilẹ̀ kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ káàkiri ní agbègbè olókè Juda. Ó fa àwọn ará Jerusalẹmu sinu aiṣododo, ó sì kó àwọn ọmọ Juda ṣìnà.
12Elija wolii kọ ìwé kan sí Jehoramu, ohun tí ó kọ sinu ìwé náà nìyí: “Gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Dafidi, baba rẹ, ti wí; ó ní, nítorí pé o kò tọ ọ̀nà tí Jehoṣafati baba rẹ tọ̀, tabi ti Asa, baba baba rẹ. 13Ṣugbọn ò ń hùwà bí àwọn ọba Israẹli, o sì ti fa àwọn Juda ati Jerusalẹmu sinu aiṣododo, bí ìdílé Ahabu ti ṣe fún Israẹli. Pataki jùlọ, o pa àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ baba rẹ, tí wọ́n tilẹ̀ sàn jù ọ́ lọ. 14Wò ó, OLUWA yóo fi àjàkálẹ̀ àrùn ṣe àwọn eniyan rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn aya rẹ ati gbogbo ohun tí o ní. 15Àrùn burúkú kan yóo kọlu ìwọ pàápàá, àrùn inú ni, yóo pọ̀, yóo sì pẹ́ lára rẹ títí tí ìfun rẹ yóo fi bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde.”
16OLUWA mú kí inú àwọn ará Filistia ati ti àwọn ará Arabia, tí wọn ń gbé nítòsí àwọn ará Etiopia, ru sí Jehoramu. 17Wọ́n dó ti Juda, wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n kó gbogbo ìṣúra tí ó wà ní ààfin lọ, pẹlu àwọn ọmọ Jehoramu ati àwọn iyawo rẹ̀. Kò ku ẹyọ ọmọ kan àfi èyí àbíkẹ́yìn tí ń jẹ́ Ahasaya.
18Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, OLUWA fi àrùn inú kan tí kò ṣe é wò bá Jehoramu jà. 19Lẹ́yìn ọdún keji tí àìsàn náà tí ń ṣe é, ìfun rẹ̀ tú síta, ó sì kú ninu ọpọlọpọ ìrora. Wọn kò dá iná ẹ̀yẹ fún un gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa ń ṣe níbi ìsìnkú àwọn baba rẹ̀.
20Ẹni ọdún mejilelọgbọn ni nígbà tí ó gorí oyè, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹjọ. Nígbà tí ó kú, kò sí ẹni tí ó sọkún, tabi tí ó ṣọ̀fọ̀ níbi òkú rẹ̀. Ìlú Dafidi ni wọ́n sin ín sí, ṣugbọn kì í ṣe ní ibojì àwọn ọba.

Currently Selected:

KRONIKA KEJI 21: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in