YouVersion Logo
Search Icon

KRONIKA KEJI 16

16
Ìyọnu De bá Israẹli
(1A. Ọba 15:17-22)
1Ní ọdún kẹrindinlogoji ìjọba Asa, ní ilẹ̀ Juda, Baaṣa ọba Israẹli gbógun ti Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi Rama láti dí ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ilẹ̀ Juda, kí ẹnikẹ́ni má baà lè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, kí àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ má sì lè jáde. 2Nítorí náà, Asa kó fadaka ati wúrà láti ilé ìṣúra ilé OLUWA ati láti ààfin ranṣẹ sí Benhadadi, ọba Siria tí ó ń gbé Damasku, ó ranṣẹ sí i pé: 3“Jẹ́ kí àjọṣepọ̀ wà láàrin wa gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láàrin àwọn baba wa. Fadaka ati wúrà yìí ni mo fi ta ọ́ lọ́rẹ; pa majẹmu tí ó wà láàrin ìwọ ati Baaṣa ọba Israẹli tì, kí ó baà lè kó ogun rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi.”
4Benhadadi gba ọ̀rọ̀ Asa, ó bá rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jáde láti lọ gbógun ti àwọn ìlú Israẹli. Wọ́n ṣẹgun Ijoni, Dani, Abeli Maimu ati gbogbo ìlú tí wọ́n kó ìṣúra pamọ́ sí ní ilẹ̀ Nafutali. 5Nígbà tí Baaṣa gbọ́ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, ó dáwọ́ odi Rama tí ó ń mọ dúró. 6Asa bá kó àwọn eniyan jọ jákèjádò Juda, wọ́n lọ kó òkúta ati pákó tí Baaṣa fi ń kọ́ Rama, wọ́n lọ fi kọ́ Geba ati Misipa.
Wolii Hanani
7Nígbà náà ni Hanani aríran, wá sọ́dọ̀ Asa, ọba Juda, ó wí fún un pé, “Nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, dípò kí o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun rẹ, àwọn ogun Siria ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. 8Ṣebí ogun Etiopia ati Libia lágbára gidigidi? Ṣebí wọ́n ní ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹlẹ́ṣin? Ṣugbọn nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn. 9Nítorí ojú OLUWA ń lọ síwá sẹ́yìn ní gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ìwà òmùgọ̀ ni èyí tí o hù yìí; nítorí pé láti ìsinsìnyìí lọ nígbàkúùgbà ni o óo máa jagun.” 10Ọ̀rọ̀ yìí mú kí inú bí Asa sí wolii Hanani, ó sì kan ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ninu túbú, nítorí inú bí i sí i fún ohun tí ó sọ. Asa ọba fi ìyà jẹ àwọn kan ninu àwọn ará ìlú ní àkókò náà.
Òpin Ìjọba Asa
(1A. Ọba 15:23-24)
11Gbogbo nǹkan tí Asa ọba ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati Israẹli. 12Ní ọdún kọkandinlogoji ìjọba Asa, àrùn burúkú kan mú un lẹ́sẹ̀, àrùn náà pọ̀ pupọ. Sibẹsibẹ, ninu àìsàn náà kàkà kí ó ké pe OLUWA fún ìwòsàn, ọ̀dọ̀ àwọn oníṣègùn ni ó lọ. 13Asa kú ní ọdún kọkanlelogoji ìjọba rẹ̀. 14Wọ́n sin ín sinu ibojì òkúta tí ó gbẹ́ fúnrarẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n tẹ́ ẹ sórí àkéte, tí ó kún fún oniruuru turari tí àwọn tí wọ́n ń ṣe turari ṣe. Wọ́n sì dá iná ńlá kan láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.

Currently Selected:

KRONIKA KEJI 16: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in