YouVersion Logo
Search Icon

ÀWỌN ỌBA KINNI 17

17
Elija ati Ọ̀dá
1Wolii kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elija, ará Tiṣibe, ní Gileadi, sọ fún Ahabu pé, “Bí OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí mò ń sìn ti wà láàyè, mò ń sọ fún ọ pé, òjò kò ní rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìrì kò ní sẹ̀ fún ọdún mélòó kan, àfi ìgbà tí mo bá sọ pé, kí òjò rọ̀, tabi kí ìrì sẹ̀.”#Jak 5:17
2Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún Elija pé, 3“Kúrò níhìn-ín, kí o doríkọ apá ìhà ìlà oòrùn, kí o sì fi ara pamọ́ lẹ́bàá odò Keriti, tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani. 4Ninu odò yìí ni o óo ti máa bu omi mu, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò kan pé kí wọ́n máa gbé oúnjẹ wá fún ọ níbẹ̀.”
5Elija bá lọ, ó ṣe bí OLUWA ti wí, ó sì ń gbé ẹ̀bá odò Keriti, ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani. 6Àwọn ẹyẹ ìwò ń gbé oúnjẹ ati ẹran wá fún un ní ojoojumọ, ní àràárọ̀ ati ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́, ó sì ń mu omi odò náà. 7Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, odò náà gbẹ nítorí àìrọ̀ òjò ní ilẹ̀ náà.
Elija ati Opó Kan, Ará Sarefati
8OLUWA bá tún sọ fún Elija pé, 9“Dìde nisinsinyii, kí o lọ sí ìlú Sarefati, ní agbègbè Sidoni, kí o sì máa gbé ibẹ̀. Mo ti pàṣẹ fún opó kan níbẹ̀ láti máa fún ọ ní oúnjẹ.”#Luk 4:25-26 10Elija bá lọ sí Sarefati. Bí ó ti dé ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú náà, ó rí obinrin opó kan tí ń wá igi ìdáná. Ó wí fún obinrin yìí pé, “Jọ̀wọ́ lọ bá mi bu omi wá kí n mu.” 11Bí ó ti ń lọ bu omi náà, Elija tún pè é pada, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi mú oúnjẹ díẹ̀ lọ́wọ́ sí i.”
12Obinrin náà dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ń gbọ́, n kò ní oúnjẹ rárá. Gbogbo ohun tí mo ní kò ju ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan lọ, tí ó wà ninu àwokòtò kan; ati ìwọ̀nba òróró olifi díẹ̀, ninu kólòbó kan. Igi ìdáná díẹ̀ ni mò ń wá níhìn-ín, kí n fi se ìwọ̀nba oúnjẹ díẹ̀ tí ó kù, fún èmi ati ọmọ mi; pé kí a jẹ ẹ́, kí a sì máa dúró de ọjọ́ ikú.”
13Elija wí fún un pé, “Má bẹ̀rù. Lọ se oúnjẹ tí o fẹ́ sè, ṣugbọn kọ́kọ́ tọ́jú díẹ̀ lára rẹ̀, kí o sì gbé e wá fún mi. Lẹ́yìn náà, kí o lọ sè fún ara rẹ ati fún ọmọ rẹ. 14Nítorí ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli wí ni pé, ìyẹ̀fun kò ní tán ninu ìkòkò rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró rẹ kò ní gbẹ títí tí OLUWA yóo fi rọ òjò sórí ilẹ̀.”
15Obinrin yìí bá lọ, ó ṣe bí Elija ti wí. Òun ati Elija ati gbogbo ará ilé rẹ̀ sì ń jẹ àjẹyó fún ọpọlọpọ ọjọ́. 16Ìyẹ̀fun kò tán ninu ìkòkò rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró rẹ̀ kò sì gbẹ, bí OLUWA ti ṣèlérí fún un láti ẹnu Elija.
17Lẹ́yìn èyí, ọmọ obinrin opó yìí ṣàìsàn. Àìsàn náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọmọ náà ṣàìsí. 18Obinrin náà bá bi Elija pé, “Eniyan Ọlọrun, kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí? Ṣé o wá sọ́dọ̀ mi láti rán Ọlọrun létí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati láti ṣe ikú pa ọmọ mi ni.”
19Elija dáhùn pé, “Gbé ọmọ náà fún mi.” Ó bá gba òkú ọmọ náà lọ́wọ́ rẹ̀, ó gbé e gun orí òkè ilé lọ sinu yàrá tí ó ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn rẹ̀. 20Ó képe OLUWA, ó ní, “OLUWA, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi jẹ́ kí irú ìdààmú yìí bá obinrin opó tí mò ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ yìí, tí o jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ kú?” 21Elija bá na ara rẹ̀ sórí ọmọ yìí nígbà mẹta, ó sì ké pe OLÚWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọ yìí tún pada sinu rẹ̀.”#2A. Ọba 4:34-35 22OLUWA dáhùn adura Elija, ẹ̀mí ọmọ náà sì tún pada sinu rẹ̀, ó sì sọjí.
23Elija gbé ọmọ náà sọ̀kalẹ̀ pada sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Wò ó! Ọmọ rẹ ti sọjí.”
24Obinrin náà sọ fún Elija pé, “Mo mọ̀ nisinsinyii pé eniyan Ọlọrun ni ọ́, ati pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA tí ń ti ẹnu rẹ jáde.”

Currently Selected:

ÀWỌN ỌBA KINNI 17: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in