YouVersion Logo
Search Icon

KỌRINTI KINNI 5

5
Paulu Ṣe Ìdájọ́ lórí Ìwà Ìbàjẹ́
1A gbọ́ dájúdájú pé ìwà àgbèrè wà láàrin yín, irú èyí tí kò tilẹ̀ sí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. A gbọ́ pé ẹnìkan ń bá iyawo baba rẹ̀ lòpọ̀!#Diut 22:30 2Dípò èyí tí ọkàn yín ìbá fi bàjẹ́, tí ẹ̀ bá sì yọ ẹni tí ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kúrò láàrin yín, ẹ wá ń ṣe fáàrí! 3-4Bí èmi alára kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín mo wà lọ́dọ̀ yín ninu ẹ̀mí. Mo ti ṣe ìdájọ́ ẹni tí ó ṣe nǹkan bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jesu Oluwa bí ẹni pé mo wà lọ́dọ̀ yín. Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, tí ẹ̀mí mi sì wà pẹlu yín, pẹlu agbára Oluwa wa Jesu, 5ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ fún Satani, kí Satani lè pa ara rẹ̀ run, kí á lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa.
6Fáàrí tí ẹ̀ ń ṣe kò dára! Ẹ kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ni ó ń mú burẹdi wú sókè?#Gal 5:9 7Ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò, kí ẹ lè dàbí burẹdi titun, ẹ óo wá di burẹdi titun ti kò ní ìwúkàrà ninu. Nítorí a ti fi Kristi ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá wa rúbọ.#Eks 12:5 8Nítorí náà ẹ jẹ́ kí á ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá wa, kì í ṣe burẹdi tí ó ní ìwúkàrà àtijọ́ ti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú ni kí á fi ṣe é, ṣugbọn pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, burẹdi ìwà mímọ́ ati òtítọ́.#Eks 13:7; Diut 16:3
9Mo kọ ìwé si yín pé kí ẹ má ṣe darapọ̀ mọ́ àwọn tí ń hùwà ìbàjẹ́. 10Kì í ṣe pé kí ẹ yẹra patapata fún àwọn alaigbagbọ tí ń hùwà àgbèrè, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi oníjìbìtì, tabi abọ̀rìṣà. Nítorí ẹ óo níláti jáde kúrò ninu ayé tí ẹ kò bá bá irú àwọn wọnyi lò. 11Ohun tí mo kọ si yín ni pé kí ẹ má ṣe darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tí a bá ń pè ní onigbagbọ tí ó ń hùwà àgbèrè, tabi ti ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó jẹ́ abọ̀rìṣà, tabi abanijẹ́, tabi ọ̀mùtí, tabi oníjìbìtì. Ẹ má tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.
12-13Èwo ni tèmi láti dá alaigbagbọ lẹ́jọ́? Ṣebí àwọn onigbagbọ ara yín ni ẹ̀ ń dá lẹ́jọ́? Ọlọrun ni ó ń ṣe ìdájọ́ àwọn alaigbagbọ. Ẹ yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín.#Diut 13:5; 17:7;

Currently Selected:

KỌRINTI KINNI 5: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in