YouVersion Logo
Search Icon

KRONIKA KINNI 2

2
Àwọn Arọmọdọmọ Juda
1Àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: Reubẹni, Simeoni, ati Lefi; Juda, Isakari, ati Sebuluni; 2Dani, Josẹfu, ati Bẹnjamini; Nafutali, Gadi ati Aṣeri.
3Juda bí ọmọ marun-un. Batiṣua, aya rẹ̀, ará Kenaani, bí ọmọ mẹta fún un: Eri, Onani ati Ṣela. Eri, àkọ́bí Juda, jẹ́ eniyan burúkú lójú OLUWA, OLUWA bá pa á. 4Tamari, iyawo ọmọ Juda, bí ọmọ meji fún un: Peresi ati Sera.
5Àwọn ọmọ Peresi ni Hesironi ati Hamuli. 6Sera bí ọmọ marun-un: Simiri, Etani, Hemani, Kalikoli ati Dada. 7Kami ni baba Akani; Akani yìí ni ó kó wahala bá Israẹli, nítorí pé ó rú òfin nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀.#Joṣ 7:1
8Etani ni ó bí Asaraya.
Ìran Dafidi Ọba
9Àwọn ọmọ Hesironi ni Jerameeli, Ramu ati Kelubai.
10Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bi Naṣoni, olórí pataki ninu ẹ̀yà Juda, 11Nahiṣoni ni baba Salima; Salima ni ó bí Boasi, 12Boasi bí Obedi, Obedi sì bí Jese.
13Jese bí ọmọ meje; orúkọ wọn nìyí bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Eliabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Abinadabu ati Ṣimea; 14Netaneli ati Radai; 15Osemu ati Dafidi. 16Àwọn arabinrin wọn ni Seruaya ati Abigaili. Seruaya yìí ló bí Abiṣai, Joabu ati Asaheli. 17Abigaili fẹ́ Jeteri láti inú ìran Iṣimaeli, ó sì bí Amasa fún un.
Ìran Hesironi
18Hesironi ni baba Kalebu. Asuba (ati Jeriotu) ni aya Kalebu yìí, Asuba bí ọmọkunrin mẹta fún un: Jeseri, Ṣobabu, ati Aridoni. 19Nígbà tí Asuba kú, Kalebu fẹ́ Efurati, Efurati sì bí Huri fún un. 20Huri ni ó bí Uri, Uri sì bí Besaleli.
21Nígbà tí Hesironi di ẹni ọgọta ọdún, ó fẹ́ ọmọbinrin Makiri, baba Gileadi. Ọmọbinrin yìí sì bí ọmọkunrin kan fún un tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Segubu. 22Segubu ni ó bí Jairi, tí ó jọba lórí ìlú ńláńlá mẹtalelogun ní ilẹ̀ Gileadi. 23Ṣugbọn Geṣuri ati Aramu gba Hafoti Jairi lọ́wọ́ rẹ̀, ati Kenati ati àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká rẹ̀; gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Makiri, baba Gileadi. 24Lẹ́yìn ìgbà tí Hesironi kú, Kalebu ṣú Efurata, iyawo baba rẹ̀ lópó, ó sì bí Aṣuri, tíí ṣe baba Tekoa.
Àwọn Ìran Jerameeli
25Jerameeli, àkọ́bí Hesironi, bí ọmọkunrin marun-un: Ramu ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Buna, Oreni, Osemu, ati Ahija. 26Jerameeli tún ní aya mìíràn, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara, òun ni ìyá Onamu. 27Àwọn ọmọ Ramu, àkọ́bí Jerameeli ni: Maasi, Jamini ati Ekeri. 28Onamu bí ọmọ meji: Ṣamai ati Jada. Ṣamai náà bí ọmọ meji: Nadabu ati Abiṣuri.
29Orúkọ aya Abiṣuri ni Abihaili, ó sì bí Ahibani ati Molidi fún un. 30Nadabu, arakunrin Abiṣuri náà bí ọmọ meji: Seledi ati Apaimu; ṣugbọn Seledi kò bímọ títí tí ó fi kú. 31Apaimu ni baba Iṣi. Iṣi bí Ṣeṣani, Ṣeṣani sì bí Ahilai.
32Jada, arakunrin Ṣamai, bí ọmọ meji: Jeteri ati Jonatani, ṣugbọn Jeteri kò bímọ títí tí ó fi kú. 33Jonatani bí ọmọ meji: Peleti ati Sasa. Àwọn ni ìran Jerameeli. 34Ṣeṣani kò bí ọmọkunrin kankan, kìkì ọmọbinrin ni ó bí; ṣugbọn Ṣeṣani ní ẹrú kan, ará Ijipti, tí ń jẹ́ Jariha. 35Ṣeṣani fi ọmọ rẹ̀ obinrin fún Jariha, ẹrú rẹ̀, ó sì bí Atai fún ẹrú náà. 36Atai ni baba Natani, Natani sì ni baba Sabadi. 37Sabadi bí Efiali, Efiali sì bí Obedi. 38Obedi ni baba Jehu, Jehu sì ni baba Asaraya. 39Asaraya ni ó bí Helesi, Helesi ni ó sì bí Eleasa. 40Eleasa bí Sisimai, Sisimai bí Ṣalumu; 41Ṣalumu bí Jekamaya, Jekamaya sì bí Eliṣama.
Àwọn Ìran Kalebu Yòókù
42Àwọn ọmọ Kalebu, arakunrin Jerameeli, nìwọ̀nyí: Mareṣa, baba Sifi ni àkọ́bí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó bí Heburoni. 43Heburoni bí ọmọ mẹrin: Kora, Tapua, Rekemu ati Ṣema. 44Ṣema bí Rahamu, Rahamu bí Jokeamu, Rekemu sì bí Ṣamai. 45Ṣamai ló bí Maoni, Maoni sì bí Betisuri.
46Kalebu tún ní obinrin kan tí ń jẹ́ Efa, ó bí ọmọ mẹta fún un: Harani, Mosa ati Gasesi. Harani bí ọmọ kan tí ń jẹ́ Gasesi.
47Àwọn ọmọ Jadai nìwọ̀nyí: Regemu, Jotamu, ati Geṣani, Peleti, Efa ati Ṣaafu.
48Kalebu tún ní obinrin mìíràn tí ń jẹ́ Maaka. Ó bí ọmọ meji fún un: Ṣeberi ati Tirihana. 49Maaka yìí kan náà ni ó bí Ṣaafu, baba Madimana, tí ó tẹ ìlú Madimana dó, ati Ṣefa, baba Makibena ati Gibea, àwọn ni wọ́n tẹ ìlú Makibena ati ìlú Gibea dó.
Kalebu tún bí ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Akisa.
50Àwọn ìran Kalebu yòókù ni: àwọn ọmọ Huri àkọ́bí Efurata, iyawo Kalebu: ati Ṣobali, baba Kiriati Jearimu; 51Salima, baba Bẹtilẹhẹmu, ati Harefu baba Betigaderi.
52Ṣobali baba Kiriati Jearimu ni baba gbogbo àwọn ará Haroe, ati ìdajì àwọn tí ń gbé Menuhotu, 53Òun náà ni baba ńlá gbogbo àwọn ìdílé tí ń gbé Kiriati Jearimu, àwọn ìdílé bíi Itiri, Puti, Ṣumati, ati Miṣirai; lára wọn ni àwọn tí wọn ń gbé ìlú Sora ati Eṣitaolu ti ṣẹ̀.
54Salima ni baba àwọn ará Bẹtilẹhẹmu, Netofati, ati ti Atirotu Beti Joabu; àwọn ará Soriti ati ìdajì àwọn ará Manahati.
55Àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé tí wọn ń gbé Jabesi nìyí: àwọn ará Tirati, Ṣimeati, ati Sukati. Àwọn ni ará Keni tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Hamati baba ńlá wọn ní ilé Rekabu.

Currently Selected:

KRONIKA KINNI 2: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in