YouVersion Logo
Search Icon

KRONIKA KINNI 1

1
Ìran Adamu títí Dé Orí Abrahamu
(Jẹn 5:1-32; 10:1-32; 11:10-26)
1Adamu bí Seti, Seti bí Enọṣi. 2Enọṣi bí Kenaani, Kenaani bí Mahalaleli, Mahalaleli bí Jaredi; 3Jaredi bí Enọku, Enọku bí Metusela, Metusela bí Lamẹki; 4Lamẹki bí Noa, Noa bí Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti.
5Àwọn ọmọ Jafẹti ni Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki ati Tirasi. 6Gomeri ni baba ńlá àwọn ọmọ Aṣikenasi, Difati ati Togama. 7Jafani ni baba ńlá àwọn ọmọ Eliṣa, Taṣiṣi, ati àwọn ará Kitimu, ati Rodọni.
8Hamu ni baba Kuṣi, Ijipti, Puti ati Kenaani, 9Kuṣi bí Ṣeba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka; Raama ni baba Ṣeba ati Dedani, 10Kuṣi bí Nimrodu. Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí ó di akikanju ati alágbára lórí ilẹ̀ ayé. 11Ijipti ni baba àwọn ará Lidia ati ti Anamu, ti Lehabu, ati ti Nafitu; 12àwọn ará Patirusimu ati ti Kasilu tíí ṣe baba ńlá àwọn ará Filistia ati àwọn ará Kafito. 13Àkọ́bí Kenaani ní Sidoni, lẹ́yìn rẹ̀ ó bí Heti, 14Kenaani yìí náà ni baba ńlá àwọn ará Jebusi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Girigaṣi; 15àwọn ará Hifi, àwọn ará Ariki ati àwọn ará Sini; 16àwọn ará Arifadi, àwọn ará Semari ati àwọn ará Hamati.
17Ṣemu ni baba Elamu, Aṣuri, ati Apakiṣadi, Ludi, Aramu, ati Usi, Huli, Geteri ati Meṣeki. 18Apakiṣadi ni baba Ṣela, Ṣela ni baba Eberi, 19Eberi bí ọmọkunrin meji: Ekinni ń jẹ́ Pelegi, (nítorí pé ní àkókò tirẹ̀ ni àwọn eniyan ayé pín sí meji); ọmọ Eberi keji sì ń jẹ́ Jokitani, 20Jokitani ni ó bí Alimodadi, Ṣelefu, Hasarimafeti, ati Jera; 21Hadoramu, Usali, ati Dikila; 22Ebali, Abimaeli, ati Ṣeba, 23Ofiri, Hafila ati Jobabu; Àwọn ni àwọn ọmọ Jokitani.
24Arọmọdọmọ Ṣemu títí fi dé orí Abramu nìyí: Ṣemu, Apakiṣadi, Ṣela; 25Eberi, Pelegi, Reu; 26Serugi, Nahori, Tẹra; 27Abramu, tí a tún ń pè ní Abrahamu.
Ìran Iṣimaeli
(Jẹn 25:12-16)
28Àwọn ọmọ Abrahamu ni Isaaki ati Iṣimaeli. 29Àkọsílẹ̀ ìran wọn nìyí: Nebaiotu ni àkọ́bí Iṣimaeli, lẹ́yìn náà ni ó bí Kedari, Adibeeli, ati Mibisamu; 30Miṣima, Duma ati Masa; Hadadi ati Tema; 31Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema.
32Abrahamu ní obinrin kan tí ń jẹ́ Ketura. Ó bí àwọn ọmọ mẹfa wọnyi fún Abrahamu: Simirani, Jokiṣani ati Medani; Midiani, Iṣibaki ati Ṣua. Àwọn ọmọ ti Jokiṣani ni: Ṣeba ati Dedani. 33Àwọn ọmọ marun-un tí Midiani bí ni Efa, Eferi ati Hanoku, Abida ati Elidaa. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Ketura.
Àwọn Ìran Esau
(Jẹn 36:1-19)
34Abrahamu ni baba Isaaki. Àwọn ọmọ Isaaki meji ni Esau ati Jakọbu. 35Àwọn ọmọ Esau ni Elifasi, Reueli, ati Jeuṣi; Jalamu ati Kora. 36Àwọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari ati Sefi; Gatamu, Kenasi, Timna ati Amaleki. 37Àwọn ọmọ Reueli ni Nahati, Sera, Ṣama ati Misa.
Àwọn tí Ń Gbé Edomu Tẹ́lẹ̀
(Jẹn 36:20-30)
38Àwọn ọmọ Seiri ni Lotani, Ṣobali ati Sibeoni; Ana, Diṣoni, Eseri ati Diṣani. 39Àwọn ọmọ Lotani ni Hori ati Homami. Lotani ní arabinrin kan tí ń jẹ́ Timna. 40Àwọn ọmọ Ṣobali ni Aliani, Manahati ati Ebali; Ṣefi ati Onamu. Sibeoni ni baba Aia ati Ana. 41Ana ni baba Diṣoni. Àwọn ọmọ Diṣoni ni Hamirani, Eṣibani, Itirani ati Kerani. 42Eseri ló bí Bilihani, Saafani ati Jaakani. Diṣani ni baba Usi ati Arani.
Àwọn Ọba Edomu
(Jẹn 36:31-43)
43Àwọn ọba tí wọ́n jẹ ní ilẹ̀ Edomu, kí ọba kankan tó jẹ ní ilẹ̀ Israẹli nìwọ̀nyí: Bela, ọmọ Beori; orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba. 44Nígbà tí Bela kú, Jobabu, ọmọ Sera, ará Bosara, jọba tẹ̀lé e. 45Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu, ará ìlú kan ní agbègbè Temani, jọba tẹ̀lé e. 46Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi, ọmọ Bedadi, tí ó ṣẹgun àwọn ará Midiani ní ilẹ̀ Moabu, jọba tẹ̀lé e. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti. 47Nígbà tí Hadadi kú, Samila ará Masireka, jọba tẹ̀lé e. 48Nígbà tí Samila kú, Ṣaulu ará Rehoboti létí odò Yufurate, jọba tẹ̀lé e. 49Nígbà tí Ṣaulu kú, Baali Hanani, ọmọ Akibori, jọba tẹ̀lé e. 50Nígbà tí Baali Hanani kú, Hadadi, jọba tẹ̀lé e. Ìlú tirẹ̀ ni Pau. Iyawo rẹ̀ ni Mehetabeli, ọmọ Matiredi, ìyá rẹ̀ àgbà ni Mesahabu. Nígbà tí ó yá, Hadadi náà kú.
51Àwọn ìjòyè ẹ̀yà Edomu nìwọ̀nyí: Timna, Alia, ati Jeteti; 52Oholibama, Ela, ati Pinoni, 53Kenasi, Temani, ati Mibisari, 54Magidieli ati Iramu.

Currently Selected:

KRONIKA KINNI 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in