1
Òwe 14:12
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú.
Compare
Explore Òwe 14:12
2
Òwe 14:30
Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara, ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.
Explore Òwe 14:30
3
Òwe 14:29
Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀, ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.
Explore Òwe 14:29
4
Òwe 14:1
Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀, ṣùgbọ́n aṣiwèrè obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀.
Explore Òwe 14:1
5
Òwe 14:26
Nínú ìbẹ̀rù OLúWA ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára, yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.
Explore Òwe 14:26
6
Òwe 14:27
Ìbẹ̀rù OLúWA jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
Explore Òwe 14:27
7
Òwe 14:16
Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.
Explore Òwe 14:16
Home
Bible
Plans
Videos