Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ,
ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́:
òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́,
ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀.
Láti sọ ọkàn wọn jí.
Nítorí n kò ní máa jà títí ayé,
tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo:
nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde,
Èmi ni mo dá èémí ìyè.