“Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín,
tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀,
gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra,
tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,
n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi,
n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi.
Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi;
nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.”