1
Luk 17:19
Bibeli Mimọ
O si wi fun u pe, Dide, ki o si mã lọ: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada.
對照
Luk 17:19 探索
2
Luk 17:4
Bi o ba si ṣẹ̀ ọ li ẹrinmeje li õjọ, ti o si pada tọ̀ ọ wá li ẹrinmeje li õjọ pe, Mo ronupiwada; dari jì i.
Luk 17:4 探索
3
Luk 17:15-16
Nigbati ọkan ninu wọn ri pe a mu on larada o pada, o si fi ohùn rara yin Ọlọrun logo. O si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o ndupẹ li ọwọ rẹ̀: ara Samaria ni on si iṣe.
Luk 17:15-16 探索
4
Luk 17:3
Ẹ mã kiyesara nyin: bi arakunrin rẹ ba ṣẹ̀, ba a wi; bi o ba si ronupiwada, dari jì i.
Luk 17:3 探索
5
Luk 17:17
Jesu si dahùn wipe, Awọn mẹwa ki a ṣo di mimọ́? Awọn mẹsan iyokù ha dà?
Luk 17:17 探索
6
Luk 17:6
Oluwa si wipe, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irugbin mustardi, ẹnyin o le wi fun igi sikamine yi pe, Ki a fà ọ tú, ki a si gbìn ọ sinu okun; yio si gbọ́ ti nyin.
Luk 17:6 探索
7
Luk 17:33
Ẹnikẹni ti o ba nwá ati gbà ẹmi rẹ̀ là yio sọ ọ nù; ẹnikẹni ti o ba si sọ ọ nù yio gbà a là.
Luk 17:33 探索
8
Luk 17:1-2
O SI wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ko le ṣe ki ohun ikọsẹ̀ má de: ṣugbọn egbé ni fun ẹniti o ti ipasẹ rẹ̀ de. Iba san fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si gbé e jù sinu okun, ju ki o mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi kọsẹ̀.
Luk 17:1-2 探索
9
Luk 17:26-27
Bi o si ti ri li ọjọ Noa, bẹ̃ni yio ri li ọjọ Ọmọ-enia. Nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn ngbeyawo, nwọn si nfà iyawo fun ni, titi o fi di ọjọ ti Noa wọ̀ inu ọkọ̀ lọ, kíkun omi si de, o si run gbogbo wọn.
Luk 17:26-27 探索
主頁
聖經
計劃
影片