Rom 8:26-39
Bẹ̃ gẹgẹ li Ẹmí pẹlu si nràn ailera wa lọwọ: nitori a kò mọ̀ bi ã ti igbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn Ẹmí tikararẹ̀ nfi irora ti a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ fun wa. Ẹniti o si nwá inu ọkàn wo, o mọ̀ ohun ti inu Ẹmí, nitoriti o mbẹbẹ fun awọn enia mimọ́ gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun. Awa si mọ̀ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ̀ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun, ani fun awọn ẹniti a pè gẹgẹ bi ipinnu rẹ̀. Nitori awọn ẹniti o ti mọ̀ tẹlẹ, li o si ti yàn tẹlẹ lati ri bi aworan Ọmọ rẹ̀, ki on le jẹ akọbi larin awọn arakunrin pupọ. Awọn ti o si ti yàn tẹlẹ, awọn li o si ti pè: awọn ẹniti o si ti pè, awọn li o si ti dalare: awọn ẹniti o si ti dalare, awọn li o si ti ṣe logo. Njẹ kili awa o ha wi si nkan wọnyi? Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa? Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ? Tani yio ha kà ohunkohun si ọrùn awọn ayanfẹ Ọlọrun? Ihaṣe Ọlọrun ti ndare? Tali ẹniti ndẹbi? Ihaṣe Kristi Jesu ti o kú, ki a sa kuku wipe ti a ti ji dide kuro ninu okú, ẹniti o si wà li ọwọ́ ọtun Ọlọrun, ti o si mbẹ̀bẹ fun wa? Tani yio ha yà wa kuro ninu ifẹ Kristi? ipọnju ni, tabi wahalà, tabi inunibini, tabi ìyan, tabi ìhoho, tabi ewu, tabi idà? Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Nitori rẹ li a ṣe npa wa kú li gbogbo ọjọ; a nkà wa si bi agutan fun pipa. Ṣugbọn ninu gbogbo nkan wọnyi awa jù ẹniti o ṣẹgun lọ nipa ẹniti o fẹ wa. Nitori o da mi loju pe, kì iṣe ikú, tabi ìye, tabi awọn angẹli, tabi awọn ijoye, tabi awọn alagbara, tabi ohun ìgba isisiyi, tabi ohun ìgba ti mbọ̀, Tabi òke, tabi ọgbun, tabi ẹda miran kan ni yio le yà wa kuro ninu ifẹ Ọlọrun, ti o wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa.
Rom 8:26-39