Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ
Sòrò Nípa “ Ìyanu Kérésimèsì Kan”!
Lèyín tí Olórun kókó se ìllérí Òlùgbàlà, Ó bèrè sí i safihàn òtító pàtó nípa oba tó ye kó wá nípasè àwon àwon ohun èlò ènìyàn: àwon wòlíì. Ju ọdún mẹ́fàọgọ́rin 680 lo kí a tó bí Jésù’, Olórun so fún wòlíì Aísáyà pé Òlùgbàlà náà yóò ní ìya wúndíá kan àtipe Yóò jé Olórun fún ara Rè ní Tara. Ìpéye ìjéwó yìí nìkan jé àgbàyanu, pàápàá ká wo oye ọdún tí ayé fi dúró fún ìmúse ìllérí náà. Sùgbón àsotélè yìí nìkan ní lara 108 tó wá símúse nípasè ìbí àti ìgbésí ayé jésù.
Ní 1958, Gbajúmọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ní ìmọ̀ Mathimátíkì àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà Peter Stoner kẹ́kọ̀ọ́ àti gbéṣirò lé àyè ìmúse àwon àsotélè tí Mèsáyá. Ó parí òrò rè pé àti seé ṣe mẹ́jọ lára àwon àsotélè108 ọgọ́rùn-ún àti méjo kó wá símúse jé, ṣíṣèdíyelé, oókan ní 100,000,000,000,000,000. Iyen jé oókan ní-ọgọ́rùn-ún àìmoye Àìlóǹkà. Méjo péré lára ọgọrun ati mẹjọ! Èyí mú Kérésìmesì jé oókan lára àwon ìyanu tó se pàtàkì jù lo ní ìtan.
Bí a se sájọyọ̀ àkókò ìsinmi yìí tó jọni lójú gan, gbìyànjú láti wé okàn rè kárí àwon àtakò gègèrè tó lòdì sí wíwá Jésù sí ayé gégé bí à se sotélè. Ní gidigidi kò seé se láti lóye! Ìdáhùn wa tó bọ́gbọ́n mu nìkan ní ìjosìn—ní ìmoore àti ìyàlẹ́nu pàtápàtá. Òrò náà so fún wa pé kò sí ààlà sí agbára Olórun,àtipe àwon nómbà wọ̀nyí jé èrí yen dájúdájú. Ó ye fún kàyéfì wa.
Àdúrà: Bàbá, È jé ìyàlẹ́nu. Mi kò tiè lè bèrè sí i lóye bí È se hun ìtan Jésù papò kí a tó bí I. Agbára àti ìmòye àìlópin Yín Yami lénu. È se fún ìyanu Omo Yín. È ràn mi lọ́wọ́ láti má lè gbójú fo bí È se tóbi tó láé.
Gbà àwòrán tónìí jáde nibi.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.
More