Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ

Advent: The Journey to Christmas

Ọjọ́ 17 nínú 25

Jé Olódodo Ní Àwon Ohun Kékeré

Olórun féran láti sisé ní ònà tó yàtò sí ojú ìwòye ayé. Kò bolá fún àwon ènìyàn fún ìdí kaánnà tí ayé n bolá fún wón. Ó pàtàkì jijẹ́ olódodo ju òkìkí lo àti ìrèlè okàn ju agbára lo. Ní alé isé ìyanu Rè tó tóbi ju lo, dípö Kó kókó fi hàn àwon oba tàbí àwon olórí ayé,Olórun rán áńgẹ́lì kan láti sò fún àwon olùṣọ́ àgùtàn tó wópò. Lúùkù 2:8 sò fún wa pé àwon olùsó àgútan ń “gbé ní pápá nítòsí, wón ń ṣọ́ àwon agbo eran wón.” kì í se ohunkóhun pé àwon okùnrin yìí jé òṣìṣẹ́ onífọkànsìn, tó n gbé nítòsí àwon àgùtàn àtipe se ìtójú tó dára fún àwon ohun tí wón fí sábé ìkáwọ́ wón áti se alámòójútó. Ìpo àwon olùsó àgútan kéré láwùjọ, sùgbón wón jé ènìyàn olódodo, àtipe Olórun yan wón láti jé ènì àkókó tó gbá ìròyìn tó tóbi ju lo ní itàn. Nígbà náà, wón wá níwàjù ìlà láti pàdé Omo Olórun ní tara!

Tí o bá nímọ̀lára pé o kò se pàtàkì tàbí a gbójú fo e lonìí, má se dékun ìdókòwò nínú ohun tí Olórun tí fún è láti se. Kódà tí o bá nímọ̀lára pé isé rè kéré, fún ní gbogbo ohun tí o ní. Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì! Olórun ń wá àwon ènìyàn tó ma jé olódodo pèlú díè kí Òun lè fi púpò sí ìkáwọ́ wón. Ohun yòówù iṣẹ́ tí àyànfún è láti se, se pèlú gbogbo agbára rè. Olórun rí ìṣòtítọ́ rè àti Yóò san èrè fáwọn tó fi tọkàntọkàn sisé tó wá níwàjù wón délẹ̀délẹ̀.

Àdúrà: Bàbá, Ẹ ṣeun fún gbigbé ìjẹ́pàtàkì lórí ohun tó dá bí ayé gbójú fo. Ohun yòówù isé tí È fún mi, mo setan láti se pèlú gbogbo okàn mi. È ràn mi lówó láti má se rẹ̀wẹ̀sì nípa àwon ìllànà ayé, àmó dípò kí rántí bí È se yan àwon onírẹ̀lẹ̀, olùsó àgútan òṣìṣẹ́ kára láti jé ènì àkókó láti mò nípa isé ìyanu Kérésìmesì. Bí àwon olùsó àgútan, È se fún yíyàn mi láti jé agbéǹkankiri Ìròyìn Yín tó dára. Àtipe È se sáájú fún fifún mi ní púpò sí i bí mo se jé olódodo pèlú ohun tí E fi si ìkáwọ́ mi.

Gbà àwòrán tónìí jáde níbí

Ọjọ́ 16Ọjọ́ 18

Nípa Ìpèsè yìí

Advent: The Journey to Christmas

Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.

More

A fé láti dúpe lówó Church of the Highlands fún ìpèsè ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí i,E jòó ṣèbẹ̀wò:https://www.churchofthehighlands.com/