Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ

Advent: The Journey to Christmas

Ọjọ́ 16 nínú 25

Okòwò Riretí Tó Kọjá iye

Nítorí àsotélè, àwon ènìyàn júù tí ńfojúsọ́nà fún olùgbàlà fún òrúndún, àtipe wón retí kábíyèsí oba tó máa dá wón sílẹ̀ lómìnira àti fìdí ìjoba tí ayé múlè. Fojú inú wò ìyàlẹ́nu àti àìgbàgbọ́ wón nígbà tí wón sò fún wòn pé a bí olùgbàlà si ebí tó wópò nínú ibùje eran ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ibi tó rẹlẹ̀ jú ní ìlú tó relè. Ohun tí àwon ènìyàn Júù gbà kò bá àwon ohun tón ńfojúsọ́nà fún pàdé.

Àmó Olórun kò si nínú okòwò ti bibá àwon ohun tón ńfojúsọ́nà sí pàdé. Ó wá ní okòwò tí fifé wón kúrò nínú omi. Jésù ní àpẹẹrẹ tó ṣòro láti gbà gbọ́ tí Olórun tó kojá iye. Nípasè Jésù, Olórun bá àwon àìní ti àwon ènîyàn Júù kò mò pé àwon ní rárá pàdé. Ó pèsè ju aásìkí tí kì í pẹ́ ti ìjoba ti ayé lo. Ó fìdí ìjoba ayérayé múlè, Ó pèsè ìgbàlà, dá àwon ènìyàn padà si ìbáṣepò ọ̀tún pèlú Olórun, àti mú ìretí tí ayé tó túká.

Ìye ìgbà melo ni a gbé àwon ohun tán ńfojúsọ́nà si lórí Olórun, ká ní pé Ó máa n sisé ní ìbámu pẹ̀lú ìlà àkókò àti ètò wa? Ìwà yìí kò dára fún ìgbàgbọ́ wa nítorí Olórun kì í sábà gbé ìgbésẹ̀ lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa, àtipe àwon ìdáhùn Rè kì í sábà bá ohun tí a rò pó máa ṣẹlẹ̀ mu.

A ní láti lóye ìyàtò láàárín gbigbé àwon ohun tán retí lórí Olórun yàtò sí ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ nínú ètò Rè àti wíwà níretí pé Yóò se de òpin ní ayé wa. Gbigbé àwon ohun tán ńfojúsọ́nà si lórí Olórun lè gbé wa kalè fún ìjákulè, ìrèwèsì, àti ìfìbínúhàn nígbà tí a kò bá rí wón gbá, sùgbón níní ìretí tó yè kooro lè bó o ìgbàgbọ́ wa.

Ifé-okàn wo ní Olórun tí gbé sí okàn rè? Ní Kérésìmesì yìí, wâ ìtùnnú ní mímo pé Olórun fé bá àwon ohun ìretí rè pàdé ju bé lo. Ó fé se kojá wón. Mu okàn le nínú ohun ìdájú gan-an pé Olórun lè se ju be lo lórí ohun tí a ronú láti béèrè láti òdò Rè. Retí Olórun láti gbé ìgbésẹ̀, ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ ìlànnà Rè, àtipe wo ìgbàgbọ́ rè dàgbà.

Àdúrà: Bàbá, E seun fún aránnilétí tí mo ní nínú Jésù pé È bá àwon àìní ti mo tilè mò pé mo ní pàdé pèlú oore òfé. Ní Kérésìmesì yìí, mo gbá àdúrà fún ìdánilójú nínú ohun tí mo retí àmó mi kò lè rí síbè. È ràn ìgbàgbó mi lọ́wọ́ nínú olùṣòtítọ́ láti pò sí. E seun fún jíjé Olórun tón se ohun tó kojá ohun tení n retí. Àkókò Yín jé pípé, àtipe ètò Yín lo dára ju lo. E ní ònà Yín ní ayé mi!

Gbà àwòrán tónìí jáde níbí.

Ọjọ́ 15Ọjọ́ 17

Nípa Ìpèsè yìí

Advent: The Journey to Christmas

Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.

More

A fé láti dúpe lówó Church of the Highlands fún ìpèsè ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí i,E jòó ṣèbẹ̀wò:https://www.churchofthehighlands.com/