Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ

Advent: The Journey to Christmas

Ọjọ́ 13 nínú 25

Se Pàtàkì Èrò Olórun Jù

Lèyín tí Olórun fi ètò Rè hàn Màríà láti jé wúndíá ìya Jésù, ó fèsì pèlú orin ìyìn àràmàǹdà. Ó fógo fún Olórun fún ìmúratán Rè láti lo èèyàn onírẹ̀lẹ̀ láti se é ète Rè tó tóbi, àtipe ó yin Olórun fún àánú Rè, jijé olóòótọ́, àti agbára ní ìmúse ìlérí Rè tí Olùgbàlà.

Oókan lara àwon ohun tó lágbára jù lo tí Màríà polongo nínú Orin yìí ní, “Láti ìsinsìnyí lọ gbogbo ìran máa pè mi ní alabùkún fún, pé Alágbára Ńlá tí se àwon ohun tó tóbi fún mi.” Èyí jé gbòlóhún alágbára tí ìgbàgbó nínú Olórun, nítorí isẹ́ tí à yàn fún un lè seé se láti mú ìdájó àti ìtìjú láti òdò fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ènì tó mò. Ta lo má gbágbó pé Màríà jé wúndíá? Àfẹ́sọ́nà rẹ̀ gan-an ní-lò ìdánilójú láti òdò ángèlì láti gbá ìtan rè gbó. Lèyín ẹgbẹ̀rún ọdún méjì àwon elómìrán sì siyèméjì lórí ijẹ́wọ́ ipò wúndíá rè.

Ní mímò pé èyí ní ìgbà, Màríà gbájú mọ́ ìbúkún tí yiyàn láti òdò Olórun fún iru ète pàtàkì náà. Ó mò pé àwon tó má gbágbó nínú Omo rè yóò bolá fún òun àti gbékèlé Òrò Olórun nípa ìṣòtítọ́ rè. Kò ronú lórí àwon ìsòro tó lè dojú ko ní àwùjo tàbí láàárìn ebí rè. Kò ní láti gbèjà ara rè. Màríà pinnu láti gbékèlé Olórun dípò kí o dènà ìpè rè, kódà tó bá túmọ̀ sí ìgbésí ayé tí àwon èèyàn kò lóye rè. Ohunkóhun tí Olórun bá béèrè lówó rè láti se, ma se jé kí èyíkéyìí inúnibíni tó lè wáyé tàbí ìdájó láti òdò àwon elómìrán mú o yera fún ìgbọràn. À kò pè wa láti je ìgbádùn, kí a tẹ́wọ́ gba wa, tàbí kí wón lóye wa. À pè wa láti mú ìyàtò wa!

Àdúrà: Bàbá, È se fún yíyàn ènì onírèlè bí emí láti lo fún Ògo Yín. Mo ní òní láti se ohunkóhun Te fé kí n se, kódà tó bá soro. Kódà tí àwon ènìyàn láyìíká mi kò lóye. Ohun tí È ro lo se pàtàkì jù si mi. Mo mò pé àwon ètò Yín níyì jù èyíkéyìí ìdènà tí mo lè kojú ní ayé yìí lo.

Gbà àwòrán tónìí jádenibi.

Ìwé mímọ́

Day 12Day 14

Nípa Ìpèsè yìí

Advent: The Journey to Christmas

Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.

More

A fé láti dúpe lówó Church of the Highlands fún ìpèsè ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí i,E jòó ṣèbẹ̀wò:https://www.churchofthehighlands.com/