Rom 5:18-19
Rom 5:18-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ìdájọ́ dé bá gbogbo ènìyàn sí ìdálẹ́bi; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nípa ìwà òdodo ẹnìkan, ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ dé sórí gbogbo ènìyàn fún ìdáláre sí ìyè. Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo.
Rom 5:18-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ bi nipa ẹ̀ṣẹ kan idajọ de bá gbogbo enia si idalẹbi; gẹgẹ bẹ̃ni nipa iwa ododo kan, ẹ̀bun ọfẹ de sori gbogbo enia fun idalare si ìye. Nitori gẹgẹ bi nipa aigbọran enia kan, enia pupọ di ẹlẹṣẹ bẹ̃ ni nipa igbọran ẹnikan, a o sọ enia pupọ di olododo.
Rom 5:18-19 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, bí òfin tí ẹnìkan rú ṣe ti gbogbo ọmọ aráyé sinu ìdájọ́ ikú, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ rere ẹnìkan yóo yọ gbogbo ọmọ aráyé ninu ìdájọ́ ikú sí ìyè. Bí a ti sọ gbogbo eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀ nítorí àìgbọràn ẹnìkan, bẹ́ẹ̀ náà ni a óo torí ìgbọràn ẹnìkan dá gbogbo eniyan láre.