O. Daf 85:7-13
O. Daf 85:7-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa fi ãnu rẹ hàn fun wa, ki o si fun wa ni igbala rẹ. Emi o gbọ́ bi Ọlọrun Oluwa yio ti wi: nitoriti yio sọ alafia si awọn enia rẹ̀, ati si awọn enia mimọ́ rẹ̀: ṣugbọn ki nwọn ki o má tun pada si were. Nitõtọ igbala rẹ̀ sunmọ́ awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀; ki ogo ki o le ma gbé ilẹ wa. Ãnu ati otitọ padera; ododo ati alafia ti fi ẹnu kò ara wọn li ẹnu. Otitọ yio rú jade lati ilẹ wá: ododo yio si bojuwò ilẹ lati ọrun wá. Nitõtọ Oluwa yio funni li eyi ti o dara; ilẹ wa yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá. Ododo yio ṣãju rẹ̀; yio si fi ipasẹ rẹ̀ ṣe ọ̀na.
O. Daf 85:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, OLúWA, Kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ. Èmi ó gbọ́ ohun tí OLúWA Ọlọ́run yóò wí; ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀: Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye. Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa. Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀; òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn. Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run. OLúWA yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́, ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde. Òdodo síwájú rẹ lọ o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.
O. Daf 85:7-13 Yoruba Bible (YCE)
Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn wá, OLUWA; kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ. Jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Ọlọrun, OLUWA yóo wí, nítorí pé ọ̀rọ̀ alaafia ni yóo sọ fún àwọn eniyan rẹ̀, àní, àwọn olùfọkànsìn rẹ̀, ṣugbọn kí wọn má yipada sí ìwà òmùgọ̀. Nítòótọ́, ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀; kí ògo rẹ̀ lè wà ní ilẹ̀ wa. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ yóo pàdé; òdodo ati alaafia yóo dì mọ́ ara wọn. Òtítọ́ yóo rú jáde láti inú ilẹ̀; òdodo yóo sì bojú wolẹ̀ láti ojú ọ̀run. Dájúdájú, OLUWA yóo fúnni ní ohun tí ó dára; ilẹ̀ wa yóo sì mú èso jáde lọpọlọpọ. Òdodo yóo máa rìn lọ níwájú rẹ̀, yóo sì sọ ipasẹ̀ rẹ̀ di ọ̀nà.