O. Daf 34:1-3
O. Daf 34:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o ma fi ibukún fun Oluwa nigbagbogbo: Iyìn rẹ̀ yio ma wà li ẹnu mi titi lai. Ọkàn mi yio ma ṣogo rẹ̀ niti Oluwa: awọn onirẹlẹ yio gbọ́, inu wọn yio si ma dùn. Gbé Oluwa ga pẹlu mi, ki a si jumọ gbé orukọ rẹ̀ leke.
Pín
Kà O. Daf 34O. Daf 34:1-3 Yoruba Bible (YCE)
N óo máa yin OLUWA ní gbogbo ìgbà; ìyìn rẹ̀ yóo máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo. OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn; kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́. Ẹ bá mi gbé OLUWA ga, ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè!
Pín
Kà O. Daf 34O. Daf 34:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò máa fi ìbùkún fún OLúWA nígbà gbogbo; ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé. Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú OLúWA; jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn. Gbé OLúWA ga pẹ̀lú mi; kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.
Pín
Kà O. Daf 34