Jer 42:1-12

Jer 42:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni gbogbo awọn olori ogun, ati Johanani, ọmọ Karea, ati Jesaniah, ọmọ Hoṣaiah, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere de ẹni-nla, nwọn wá, Nwọn si sọ fun Jeremiah woli, pe, Awa bẹ ọ, jẹ ki ẹ̀bẹ wa ki o wá siwaju rẹ, ki o si gbadura fun wa si Oluwa Ọlọrun rẹ, ani fun gbogbo iyokù yi; (nitori lati inu ọ̀pọlọpọ, diẹ li awa kù, gẹgẹ bi oju rẹ ti ri wa:) Ki Oluwa Ọlọrun rẹ le fi ọ̀na hàn wa ninu eyi ti awa iba rìn, ati ohun ti awa iba ṣe. Jeremiah, woli, si wi fun wọn pe, emi gbọ́; wò o, emi o gbadura si Oluwa Ọlọrun nyin gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin; yio si ṣe, pe ohunkohun ti Oluwa yio fi da nyin lohùn emi o sọ ọ fun nyin; emi kì o ṣẹ nkankan kù fun nyin. Nwọn si wi fun Jeremiah pe, ki Oluwa ki o ṣe ẹlẹri otitọ ati ododo lãrin wa, bi awa kò ba ṣe gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa, Ọlọrun rẹ, yio rán ọ si wa. Iba ṣe rere, iba ṣe ibi, awa o gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, sọdọ ẹniti awa rán ọ: ki o le dara fun wa, bi awa ba gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́. O si ṣe lẹhin ọjọ mẹwa li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá. Nigbana ni o pè Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere titi de ẹni-nla. O si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, sọdọ ẹniti ẹnyin rán mi, lati mu ẹ̀bẹ nyin wá siwaju rẹ̀; Bi ẹnyin o ba gbe ilẹ yi lõtọ, nigbana ni emi o gbe nyin ro emi kì yio si fà nyin lulẹ, emi o si gbìn nyin, emi kì yio si fà nyin tu: nitori emi yi ọkàn pada niti ibi ti emi ti ṣe si nyin. Ẹ má bẹ̀ru ọba Babeli, ẹniti ẹnyin mbẹ̀ru: ẹ máṣe bẹ̀ru rẹ̀, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu nyin lati ràn nyin lọwọ, ati lati gbà nyin li ọwọ rẹ̀. Emi o si fi ãnu hàn fun nyin, ki on ki o le ṣãnu fun nyin, ki o si mu ki ẹnyin pada si ilẹ nyin.

Jer 42:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn olórí ogun ati Johanani, ọmọ Karea ati Asaraya, ọmọ Hoṣaaya, ati gbogbo àwọn ará Juda, lọ́mọdé ati lágbà, tọ wolii Jeremaya lọ. Wọ́n wí fún un pé, “Nǹkan kan ni a fẹ́ bẹ̀ ọ́ fún, a sì fẹ́ kí o ṣe é fún wa: jọ̀wọ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ fún àwa ati gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, nítorí pé a ti pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn díẹ̀ ninu wa ni ó kù, bí ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí i. A fẹ́ kí OLUWA Ọlọrun rẹ lè fi ọ̀nà tí a óo gbà hàn wá, kí ó sọ ohun tí a óo ṣe fún wa.” Wolii Jeremaya bá dá wọn lóhùn pé, “Mo gbọ́, n óo gbadura sí OLUWA Ọlọrun yín bí ẹ ti wí; gbogbo ìdáhùn tí OLUWA bá fún mi ni n óo sọ fun yín, n kò ní fi nǹkankan pamọ́.” Wọ́n wí fún Jeremaya pé, “Kí OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ ati òdodo bí a kò bá ṣe gbogbo nǹkan tí OLUWA Ọlọrun bá ní kí o sọ fún wa. Ìbáà jẹ́ rere ni OLUWA Ọlọrun wa tí a rán ọ sí sọ, kì báà jẹ́ burúkú, a óo gbọ́ràn sí i lẹ́nu; kí ó lè dára fún wa; nítorí pé ti OLUWA Ọlọrun wa ni a óo gbọ́.” Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwaa, OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀. Jeremaya bá pe Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ẹ ní kí n gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ siwaju rẹ̀ ní, ‘Bí ẹ bá dúró ní ilẹ̀ yìí, n óo kọ yín bí ilé, n kò sì ní wo yín lulẹ̀. N óo gbìn yín bí igi, n kò sì ní fà yín tu, nítorí mo ti yí ọkàn mi pada nípa ibi tí mo ṣe sí yín. Ẹ má bẹ̀rù ọba Babiloni tí ẹrù rẹ̀ ń bà yín, ẹ má bẹ̀rù rẹ̀; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, nítorí pé mo wà pẹlu yín. N óo gbà yín là n óo sì yọ yín lọ́wọ́ rẹ̀. N óo ṣàánú yín, n óo jẹ́ kí ó ṣàánú yín, kí ó sì jẹ́ kí ẹ máa gbé orí ilẹ̀ yín.’

Jer 42:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ní gbogbo àwọn olórí ogun àti Johanani ọmọkùnrin Karea àti Jesaniah ọmọkùnrin Hoṣaiah àti kékeré títí dé orí ẹni ńlá wá. Sí ọ̀dọ̀ Jeremiah wòlíì náà, wọ́n sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì gbàdúrà sí OLúWA Ọlọ́run rẹ fún gbogbo ìyókù yìí. Nítorí gẹ́gẹ́ bi ìwọ ṣe rí i nísinsin yìí pé a pọ̀ níye nígbà kan rí; ṣùgbọ́n báyìí àwa díẹ̀ la ṣẹ́kù Gbàdúrà pé kí OLúWA Ọlọ́run rẹ sọ ibi tí àwa yóò lọ fún wa àti ohun tí àwa yóò ṣe.” Wòlíì Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Mo ti gbọ́. Èmi yóò gbàdúrà sí OLúWA Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ṣe béèrè. Èmi yóò sọ gbogbo ohun tí OLúWA bá sọ fún un yín, ń kò sì ní fi ohunkóhun pamọ́ fún un yín.” Nígbà náà ni wọ́n sọ fún Jeremiah wí pé, “Kí OLúWA ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ àti òdodo láàrín wa, bí àwa kò bá ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí OLúWA Ọlọ́run rẹ bá rán ọ láti sọ fún wa. Ìbá à ṣe rere, ìbá à ṣe búburú, àwa yóò gbọ́rọ̀ sí OLúWA Ọlọ́run wa; èyí tí àwa ń rán ọ sí; Kí ó ba à lè dára fún wa. Nítorí pé àwa yóò gbọ́rọ̀ sí OLúWA Ọlọ́run wa.” Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ Jeremiah wá wí pé; Nígbà náà ni a ó pa Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀; àti gbogbo àwọn ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni ńlá. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: ‘Èyí ni ẹni tí ẹ̀yin ti rán láti gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ síwájú mi. Bí ẹ̀yin bá gbé ní ilẹ̀ yìí, èmi yóò gbé e yín ró, n kò sí ní fà yín lulẹ̀, èmi yóò gbìn yín, n kì yóò fà yín tu nítorí wí pé èmi yí ọkàn padà ní ti ibi tí mo ti ṣe sí i yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọba Babeli tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni OLúWA wí; nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbà yín ní ọwọ́ rẹ̀. Èmi yóò fi àánú hàn sí i yín, kí ó lè ṣàánú fún un yín, kí ó sì mú un yín padà sí ilẹ̀ yín.’