Jer 1:9-14
Jer 1:9-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa si nà ọwọ rẹ̀, o fi bà ẹnu mi; Oluwa si wi fun mi pe, sa wò o, emi fi ọ̀rọ mi si ọ li ẹnu. Wò o, li oni yi ni mo fi ọ ṣe olori awọn orilẹ-ède, ati olori ijọba wọnni, lati fàtu, ati lati fà lulẹ; lati parun, ati lati wó lulẹ; lati kọ́, ati lati gbìn. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe, Jeremiah, kini iwọ ri? emi si wipe, mo ri ọpa igi almondi. Oluwa si wi fun mi pe, iwọ riran rere, nitori ti emi o kiye si ọ̀rọ mi lati mu u ṣẹ. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá lẹ̃keji pe, kini iwọ ri? emi si wipe, mo ri ìkoko ori iná, oju rẹ̀ si ni lati iha ariwa wá. Nigbana ni Oluwa sọ fun mi pe, ibi yio tú jade lati ariwa wá, sori gbogbo awọn ti ngbe inu ilẹ.
Jer 1:9-14 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá na ọwọ́, ó fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu. Mo ti fi ọ́ ṣe orí fún àwọn orílẹ̀-èdè ati ìjọba lónìí, láti fà wọ́n tu ati láti bì wọ́n lulẹ̀, láti pa wọ́n run ati láti bì wọ́n ṣubú, láti tún wọn kọ́ ati láti gbé wọn ró.” OLUWA bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí yìí?” Mo dáhùn, pé, “Ọ̀pá igi Alimọndi ni.” OLUWA bá wí fún mi pé, “Òtítọ́ ni ohun tí o rí, nítorí mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, n óo sì mú un ṣẹ.” OLUWA tún bi mí lẹẹkeji, ó ní, “Kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé, “Mo rí ìkòkò kan tí ó ń hó lórí iná, ó tẹ̀ láti ìhà àríwá sí ìhà gúsù.” OLUWA bá sọ fún mi pé, “Láti ìhà àríwá ni ibi yóo ti dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà.
Jer 1:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn. Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ mí wá wí pé: “Kí ni o rí Jeremiah?” Mo sì dáhùn wí pé “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.” OLúWA sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.” Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ̀kejì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá. OLúWA, sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà.