Isa 6:1-6
Isa 6:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọdun ti Ussiah ọba kú, emi ri Oluwa joko lori itẹ ti o ga, ti o si gbe ara soke, iṣẹti aṣọ igunwà rẹ̀ kun tempili. Awọn serafu duro loke rẹ̀: ọkọ̃kan wọn ni iyẹ mẹfa, o fi meji bò oju rẹ̀, o si fi meji bò ẹsẹ rẹ̀, o si fi meji fò. Ikini si ke si ekeji pe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, li Oluwa awọn ọmọ-ogun, gbogbo aiye kún fun ogo rẹ̀. Awọn òpo ilẹ̀kun si mì nipa ohùn ẹniti o ke, ile na si kún fun ẹ̃fin. Nigbana ni mo wipe, Egbe ni fun mi, nitori mo gbé, nitoriti mo jẹ́ ẹni alaimọ́ etè, mo si wà lãrin awọn enia alaimọ́ etè, nitoriti oju mi ti ri Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun. Nigbana ni ọkan ninu awọn serafu fò wá sọdọ mi, o ni ẹṣẹ́-iná li ọwọ́ rẹ̀, ti o ti fi ẹmú mu lati ori pẹpẹ wá.
Isa 6:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọdún tí Usaya Ọba kú, mo rí OLUWA: ó jókòó lórí ìtẹ́, a gbé e ga sókè, aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. Àwọn Serafu dúró lókè rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ìyẹ́ mẹfa mẹfa: ó fi meji bo ojú, ó fi meji bo ẹsẹ̀, ó sì ń fi meji fò. Ekinni ń ké sí ekeji pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun; gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.” Ìpìlẹ̀ ilé náà mì títí nígbà tí ẹni náà kígbe, èéfín sì kún ilé náà. Mo bá pariwo, mo ní, “Mo gbé! Mo ti sọnù, nítorí pé ọ̀rọ̀ ẹnu mi kò mọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tí mò ń gbé ààrin wọn náà kò sì mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo ti fi ojú rí Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun.” Ọ̀kan ninu àwọn Serafu náà bá fi ẹ̀mú mú ẹ̀yinná kan lórí pẹpẹ, ó mú un lọ́wọ́, ó bá fò wá sọ́dọ̀ mi.
Isa 6:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.” Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín. Mo kígbe pé “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, OLúWA àwọn ọmọ-ogun jùlọ. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn Serafu wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀yín iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní orí pẹpẹ.