Gẹn 39:1-23

Gẹn 39:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

A SI mú Josefu sọkalẹ wá si Egipti; Potifari, ijoye Farao kan, olori ẹṣọ́, ara Egipti, si rà a lọwọ awọn ara Iṣmaeli ti o mú u sọkalẹ wá sibẹ̀. OLUWA si wà pẹlu Josefu, o si ṣe alasiki enia; o si wà ni ile oluwa rẹ̀ ara Egipti na. Oluwa rẹ̀ si ri pe OLUWA pẹlu rẹ̀, ati pe, OLUWA mu ohun gbogbo ti o ṣe dara li ọwọ́ rẹ̀. Josefu si ri ojurere li oju rẹ̀, on si nsìn i: o si fi i jẹ́ olori ile rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní on li o fi lé e lọwọ. O si ṣe lati ìgba ti o ti fi Josefu jẹ́ olori ile rẹ̀, ati olori ohun gbogbo ti o ní, ni OLUWA busi ile ara Egipti na nitori Josefu: ibukún OLUWA si wà lara ohun gbogbo ti o ní ni ile ati li oko. O si fi ohun gbogbo ti o ní si ọwọ́ Josefu; kò si mọ̀ ohun ti on ní bikoṣe onjẹ ti o njẹ. Josefu si ṣe ẹni daradara ati arẹwà enia. O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni aya oluwa rẹ̀ gbé oju lé Josefu; o si wipe, Bá mi ṣe. Ṣugbọn on kọ̀, o si wi fun aya oluwa rẹ̀ pe, kiyesi i, oluwa mi kò mọ̀ ohun ti o wà lọdọ mi ni ile, o si ti fi ohun gbogbo ti o ní lé mi lọwọ: Kò sí ẹniti o pọ̀ jù mi lọ ninu ile yi; bẹ̃ni kò si pa ohun kan mọ́ kuro lọwọ mi bikoṣe iwọ, nitori pe aya rẹ̀ ni iwọ iṣe: njẹ emi o ha ti ṣe hù ìwabuburu nla yi, ki emi si dẹ̀ṣẹ si Ọlọrun? O si ṣe, bi o ti nsọ fun Josefu lojojumọ́, ti on kò si gbọ́ tirẹ̀ lati dubulẹ tì i, tabi lati bá a ṣe. O si ṣe niwọ̀n akokò yi, ti Josefu wọle lọ lati ṣe iṣẹ rẹ̀; ti kò si sí ẹnikan ninu awọn ọkunrin ile ninu ile nibẹ̀. On si di Josefu li aṣọ mú, o wipe, bá mi ṣe: on si jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, o si sá, o bọ sode. O si ṣe, nigbati o ri i pe Josefu jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, ti o si sá jade, Nigbana li o kepè awọn ọkunrin ile rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ wò o, o mú Heberu kan wọle tọ̀ wa wá lati fi wa ṣe ẹlẹyà; o wọle tọ̀ mi wá lati bá mi ṣe, mo si kigbe li ohùn rara: O si ṣe, nigbati o gbọ́ pe mo gbé ohùn mi soke ti mo si kigbe, o jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá, o bọ sode. O si fi aṣọ Josefu lelẹ li ẹba ọdọ rẹ̀, titi oluwa rẹ̀ fi bọ̀wá ile. O si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi pe, Ẹrú Heberu ti iwọ mu tọ̀ wá wá, o wọle tọ̀ mi lati fi mi ṣe ẹlẹyà: O si ṣe, bi mo ti gbé ohùn mi soke ti mo si ké, o si jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá jade. O si ṣe, nigbati oluwa rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ aya rẹ̀, ti o sọ fun u wipe, Bayibayi li ẹrú rẹ ṣe si mi; o binu gidigidi. Oluwa Josefu si mú u, o si fi i sinu túbu, nibiti a gbé ndè awọn ara túbu ọba; o si wà nibẹ̀ ninu túbu. Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josefu, o si ṣãnu fun u, o si fun u li ojurere li oju onitúbu. Onitúbu si fi gbogbo awọn ara túbu ti o wà ninu túbu lé Josefu lọwọ; ohunkohun ti nwọn ba si ṣe nibẹ̀, on li oluṣe rẹ̀. Onitúbu kò si bojuwò ohun kan ti o wà li ọwọ́ rẹ̀; nitori ti OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati ohun ti o ṣe OLUWA mú u dara.

Gẹn 39:1-23 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ará Iṣimaeli mú Josẹfu lọ sí Ijipti, wọ́n sì tà á fún Pọtifari ará Ijipti. Pọtifari yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè Farao, òun sì tún ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba. OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ninu ilé ọ̀gá rẹ̀, ará Ijipti, níbi tí ó ń gbé. Àwọn ohun tí ó ń ṣe sì ń yọrí sí rere. Ọ̀gá rẹ̀ ṣàkíyèsí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati pé OLUWA ń bukun ohun gbogbo tí ó bá dáwọ́lé. Nítorí náà, ó rí ojurere Pọtifari. Pọtifari mú un sọ́dọ̀ pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún òun, ó fi ṣe alabojuto gbogbo ilé rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ rẹ̀. Nígbà tí Pọtifari ti fi Josẹfu ṣe alabojuto ilé rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí bukun ìdílé Pọtifari, ará Ijipti náà, ati ohun gbogbo tí ó ní nítorí ti Josẹfu. Nítorí náà, ó fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ Josẹfu níwọ̀n ìgbà tí ó wà pẹlu rẹ̀, kò sì bìkítà fún ohunkohun mọ́, àfi oúnjẹ tí ó ń jẹ. Josẹfu ṣígbọnlẹ̀, ó sì lẹ́wà. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Josẹfu wu aya ọ̀gá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ ọ́ pé kí ó wá bá òun lòpọ̀. Ṣugbọn Josẹfu kọ̀, ó wí fún un pé, “Wò ó, níwọ̀n ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ ọ̀gá mi, kò bìkítà fún ohunkohun ninu ilé yìí, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ mi. Kò sí ohun tí ó fi jù mí lọ ninu ilé yìí, kò sì sí ohun tí kò fi lé mi lọ́wọ́, àfi ìwọ nìkan, nítorí pé aya rẹ̀ ni ọ́. Ǹjẹ́ ó tọ́ sí mi láti ṣe irú ohun burúkú yìí kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lojoojumọ ni ó ń rọ Josẹfu, sibẹsibẹ, Josẹfu kò gbà láti bá a lòpọ̀, tabi láti wà pẹlu rẹ̀. Ṣugbọn ní ọjọ́ kan nígbà tí Josẹfu wọ inú ilé lọ láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni nílé ninu àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Obinrin yìí so mọ́ ọn lẹ́wù, ó ní, “Wá bá mi lòpọ̀.” Ṣugbọn Josẹfu bọ́rí kúrò ninu ẹ̀wù rẹ̀, ó sá jáde kúrò ninu ilé. Nígbà tí ó rí i pé Josẹfu fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ati pé ó sá jáde kúrò ninu ilé, ó pe àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀, ó sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ wo nǹkan, ọkọ mi ni ó mú Heberu yìí wá láti wá fi ẹ̀gbin lọ̀ wá. Ó wọlé wá bá mi láti bá mi lòpọ̀, ni mo bá pariwo. Nígbà tí ó sì rí i pé mo pariwo, ó sá jáde, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́.” Obinrin náà bá fi ẹ̀wù rẹ̀ sọ́dọ̀ títí tí ọ̀gá rẹ̀ fi wọlé dé. Nígbà tí ó dé, obinrin yìí sọ ohun kan náà fún un, ó ní, “Ẹrú ará Heberu tí o mú wá sí ààrin wa, ni ó déédé wọlé tọ̀ mí wá láti fi ẹ̀gbin lọ̀ mí, ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé mo pariwo, ó ju ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́, ó sá jáde.” Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí ẹrú rẹ ti ṣe sí mi nìyí” inú bí i gidigidi, ó sì sọ Josẹfu sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ibi tí wọn ń ti àwọn tí ọba bá sọ sí ẹ̀wọ̀n mọ́ ni wọ́n tì í mọ́. Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ hàn sí i, ó jẹ́ kí ó bá ojurere alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà pàdé. Alabojuto náà fi Josẹfu ṣe olùdarí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ẹ̀wọ̀n, ohunkohun tí Josẹfu bá sọ, ni wọ́n ń ṣe. Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kì í fi nǹkan lé Josẹfu lọ́wọ́ kí ó tún bìkítà fún un mọ́, nítorí pé OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ohunkohun tí ó bá ṣe, OLUWA ń jẹ́ kí ó yọrí sí rere.

Gẹn 39:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí wọ́n mú Josẹfu dé Ejibiti, Potiferi, ará Ejibiti tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao. Òun ni olórí àwọn ọmọ-ogun Farao. Ó ra Josẹfu lọ́wọ́ àwọn ará Iṣmaeli tí wọ́n mú un lọ síbẹ̀. OLúWA sì wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì bùkún un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Ejibiti. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé OLúWA wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé OLúWA jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé. Josẹfu sì rí ojúrere Potiferi, ó sì di aṣojú rẹ̀, Potiferi fi Josẹfu ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún OLúWA wà lórí gbogbo ohun tí Potiferi ní, nílé àti lóko. Ó sì fi Josẹfu ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu ṣe àkóso ilé e rẹ̀. Josẹfu sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀, lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Josẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà. Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí. Ó sì di aṣọ Josẹfu mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde. Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde, ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Heberu kan wọlé tọ̀ wá wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lòpọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe. Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sókè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.” Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé. Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará Heberu tí o rà wá ilé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lòpọ̀. Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.” Nígbà tí Potiferi gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi. Ó sì ju Josẹfu sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Josẹfu wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀, OLúWA sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ṣàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n (wọ́dà). Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Josẹfu ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń ṣe níbẹ̀. Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Josẹfu, nítorí pé OLúWA wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé.