I. Tim 6:11-20
I. Tim 6:11-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn iwọ enia Ọlọrun, sá fun nkan wọnyi; ki o si mã lepa ododo, ìwa-bi-Ọlọrun, igbagbọ́, ifẹ, sũru, ìwa tutù. Mã jà ìja rere ti igbagbọ́, di ìye ainipẹkun mu ninu eyiti a gbé pè ọ si, ti iwọ si ṣe ijẹwo rere niwaju ẹlẹri pupọ̀. Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ti nsọ ohun gbogbo di ãye, ati niwaju Jesu Kristi, ẹni, niwaju Pontiu Pilatu, ti o jẹri ijẹwọ rere, Ki iwọ ki o pa ofin mọ́ li ailabawọn, li ailẹgan, titi di ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi: Eyiti yio fihàn ni igba tirẹ̀, Ẹniti iṣe Olubukún ati Alagbara na kanṣoṣo, Ọba awọn ọba, ati Oluwa awọn oluwa; Ẹnikanṣoṣo ti o ni aikú, ti ngbe inu imọlẹ ti a kò le sunmọ, ẹniti enia kan kò ri rí ti kò si le ri: ẹniti ọla ati agbara titi lai iṣe tirẹ. Amin. Kìlọ fun awọn ti o lọrọ̀ li aiye isisiyi, ki nwọn máṣe gberaga, bẹni ki nwọn máṣe gbẹkẹle ọrọ̀ aidaniloju, bikoṣe le Ọlọrun alãye, ti nfi ohun gbogbo fun wa lọpọlọpọ lati lo; Ki nwọn ki o mã ṣõre, ki nwọn ki o mã pọ̀ ni iṣẹ rere, ki nwọn mura lati pin funni, ki nwọn ki o ni ẹmi ibakẹdun; Ki nwọn ki o mã tò iṣura ipilẹ rere jọ fun ara wọn dè igba ti mbọ̀, ki nwọn ki o le di ìye tõtọ mu. Timotiu, ṣọ ohun ni ti a fi si itọju rẹ, yà kuro ninu ọ̀rọ asan ati ijiyan ohun ti a nfi eke pè ni imọ
I. Tim 6:11-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù. Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀. Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọntiu Pilatu, Kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi. Èyí ti yóò fihàn ní ìgbà tirẹ̀, Ẹni tí í ṣe Olùbùkún àti Alágbára kan ṣoṣo náà, ọba àwọn ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí, tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀. Àmín. Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ láti lò; Kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fún ni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbá kẹ́dùn; kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú. Timotiu, máa ṣọ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ni ìmọ̀
I. Tim 6:11-20 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ìwọ eniyan Ọlọrun, sá fún nǹkan wọnyi. Máa lépa òdodo, ati ìfọkànsìn Ọlọrun, igbagbọ, ìfẹ́, ìfaradà, ati ìwà pẹ̀lẹ́. Máa ja ìjà rere ti igbagbọ. Di ìyè ainipẹkun mú. Ohun tí Ọlọrun pè ọ́ fún nìyí, òun sì ni ẹ̀rí rere tí o fi ẹnu ara rẹ jẹ́ níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí. Mo pá a láṣẹ fún ọ níwájú Ọlọrun tí ó fi ẹ̀mí sinu gbogbo ohun alààyè, ati níwájú Kristi Jesu tí òun náà jẹ́rìí rere níwájú Pọntiu Pilatu, pé kí o mú gbogbo àṣẹ tí o ti gbà ṣẹ láìsí àléébù ati láìsí ẹ̀gàn títí Oluwa wa Jesu Kristi yóo fi farahàn. Ọlọrun yóo mú ìfihàn yìí wá ní àkókò tí ó bá wù ú, òun ni aláṣẹ kanṣoṣo, Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn oluwa; òun nìkan tí kì í kú, tí ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí eniyan kò lè súnmọ́, tí ẹnikẹ́ni kò rí rí, tí eniyan kò tilẹ̀ lè rí. Tirẹ̀ ni ọlá ati agbára tí kò lópin. Amin. Mo pa á láṣẹ fún àwọn ọlọ́rọ̀ ayé yìí, pé kí wọ́n má ṣe ní ọkàn gíga. Bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe gbára lé ọrọ̀ tí kò lágbẹkẹ̀lé, ṣugbọn kí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun tí ó ń fún wa ní gbogbo ọrọ̀ fún ìgbádùn wa. Kí wọn máa ṣe rere, kí wọn jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu iṣẹ́ rere, kí wọn fẹ́ràn láti máa ṣe ọrẹ ati láti máa mú ninu ohun ìní wọn fún àwọn ẹlòmíràn, kí wọ́n lè ní ìṣúra fún ara wọn tí yóo jẹ́ ìpìlẹ̀ rere fún ẹ̀yìn ọ̀la, kí ọwọ́ wọn lè tẹ ìyè tòótọ́. Timoti mi ọ̀wọ́n, pa ìṣúra tí a fi fún ọ mọ́. Di etí rẹ sí àwọn ọ̀rọ̀ játijàti tí kò ṣeni ní anfaani ati àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn kan ń ṣì pè ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n. Àṣìpè ni, nítorí pé wọ́n kún fún àwọn ẹ̀kọ́ tí ó lòdì sí ara wọn.