I. A. Ọba 10:1-8

I. A. Ọba 10:1-8 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba gbọ́ òkìkí ọgbọ́n Solomoni, ó wá sí Jerusalẹmu láti fi àwọn ìbéèrè tí ó takókó dán an wò. Ó kó ọpọlọpọ iranṣẹ lẹ́yìn, ó sì di turari olóòórùn dídùn, pẹlu òkúta olówó iyebíye ati ọpọlọpọ wúrà ru ọpọlọpọ ràkúnmí; ó wá sí Jerusalẹmu. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ patapata fún un. Solomoni dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè rẹ̀, kò sì sí ohunkohun tí ó le fún Solomoni láti ṣàlàyé. Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba rí i bí Solomoni ti gbọ́n tó, ati irú ààfin tí ó kọ́, irú oúnjẹ tí ó wà lórí tabili rẹ̀, ìjókòó àwọn ìjòyè rẹ̀, ìṣesí àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ìwọṣọ wọn, àwọn tí wọ́n ń gbé ọtí rẹ̀ ati ẹbọ sísun tí ó ń rú ninu ilé OLUWA, ẹnu yà á lọpọlọpọ. Ó sọ fún Solomoni ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa ìjọba rẹ ati ọgbọ́n rẹ. Ṣugbọn n kò gbàgbọ́ títí tí mo fi wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Àwọn tí wọ́n sọ fún mi kò tilẹ̀ sọ ìdajì ohun tí mo rí. Ọgbọ́n, ati ọrọ̀ rẹ pọ̀ rékọjá ohun tí mo gbọ́ lọ. Àwọn iyawo rẹ ṣe oríire; bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi tí wọn ń wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo, tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n rẹ!

I. A. Ọba 10:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ òkìkí Solomoni àti ì bà ṣe pọ̀ rẹ̀ ní ti orúkọ OLúWA, ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle. Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńláńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀. Solomoni sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un. Nígbà tí ayaba Ṣeba sì rí gbogbo ọgbọ́n Solomoni àti ààfin tí ó ti kọ́. Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ sísun tí ó sun ní ilé OLúWA, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́! Ó sì wí fún ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní orílẹ̀-èdè mi ní ti iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ. Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Sì kíyèsi i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi; ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́. Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ!