Marku 11:27, 28, 29, 30, 31, 32, 33
Marku 11:27 YCB
Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ni tẹmpili, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Júù wá sọ́dọ̀ rẹ̀.
Marku 11:28 YCB
Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Àṣẹ wo ni ó fi ń ṣe nǹkan yìí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyí?”
Marku 11:29 YCB
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi yóò bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan, kí ẹ sì dá mi lóhùn, èmi yóò sọ fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”
Marku 11:30 YCB
Ìtẹ̀bọmi Johanu láti ọ̀run wa ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn? “Ẹ dá mi lóhùn!”
Marku 11:31 YCB
Wọ́n bá ara wọn jíròrò pé: “Bí a bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun ó wí pé, ‘nígbà tí ẹ mọ̀ bẹ́ẹ̀, èéṣe tí ẹ kò fi gbà à gbọ́?’
Marku 11:32 YCB
Ṣùgbọ́n bí a bá wí pé, Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí pé gbogbo ènìyàn ló gbàgbọ́ pé wòlíì gidi ni Johanu.”
Marku 11:33 YCB
Nítorí náà, Wọ́n kọjú sí Jesu wọn sì dáhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò lè dáhùn ìbéèrè mi, Èmi náà kì yóò sọ fún yín àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”