Matiu 21:1, 2, 3, 4, 5, 6, 7, 8, 9, 10, 11
Matiu 21:1 YCB
Bí wọ́n ti súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé itòsí ìlú Betfage ní orí òkè Olifi, Jesu sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì
Matiu 21:2 YCB
Ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tó wà ni tòsí yín, ẹ̀yin yóò rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ti wọ́n so pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi.
Matiu 21:3 YCB
Bí ẹnikẹ́ni bá sì béèrè ìdí tí ẹ fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sá à wí pé, Olúwa fẹ́ lo wọn, òun yóò sì rán wọn lọ.”
Matiu 21:5 YCB
“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé, ‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ”
Matiu 21:6 YCB
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sí lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti sọ fún wọn
Matiu 21:7 YCB
Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, wọ́n tẹ́ aṣọ lé e, Jesu si jókòó lórí rẹ̀.
Matiu 21:8 YCB
Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà.
Matiu 21:9 YCB
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi!” “Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!” “Hosana ní ibi gíga jùlọ!”
Matiu 21:10 YCB
Bí Jesu sì ti ń wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, “Ta nìyìí?”
Matiu 21:11 YCB
Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì dáhùn pé, “Èyí ni Jesu, wòlíì náà láti Nasareti ti Galili.”