Sek 12
12
Ìlérí Ìdáǹdè fún Jerusalẹmu
1Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa fun Israeli, li Oluwa wi, ẹni ti o nnà awọn ọrun, ti o si fi ipilẹ aiye sọlẹ, ti o si mọ ẹmi enia ti mbẹ ni inu rẹ̀.
2Kiye si i, emi o sọ Jerusalemu di ago iwarìri si gbogbo enia yika, nigbati nwọn o do tì Juda ati Jerusalemu.
3Li ọjọ na li emi o sọ Jerusalemu di ẹrù okuta fun gbogbo enia: gbogbo awọn ti o ba si fi dẹrù pa ara wọn li a o ke si wẹwẹ, bi gbogbo awọn orilẹ-ède aiye tilẹ ko ara wọn jọ si i.
4Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o fi itagìri lù gbogbo ẹṣin, ati fi wère lu ẹniti ngùn u; emi o si ṣi oju mi si ile Juda, emi o si bu ifọju lù gbogbo ẹṣin ti enia na.
5Ati awọn bãlẹ Juda yio si wi li ọkàn wọn pe, Awọn ara Jerusalemu li agbara mi nipa Oluwa Ọlọrun wọn.
6Li ọjọ na li emi o ṣe awọn bãlẹ Juda bi ãrò iná kan lãrin igi, ati bi ètùfù iná lãrin ití; nwọn o si jẹ gbogbo awọn enia run yika lapa ọ̀tun ati lapa osi: a o si tun ma gbe Jerusalemu ni ipo rẹ̀, ani Jerusalemu.
7Oluwa pẹlu yio kọ́ tète gba agọ Juda là na, ki ogo ile Dafidi ati ogo awọn ara Jerusalemu ma bà gbe ara wọn ga si Juda.
8Li ọjọ na li Oluwa yio dãbò bò awọn ti ngbe Jerusalemu; ẹniti o ba si ṣe ailera ninu wọn li ọjọ na yio dabi Dafidi; ile Dafidi yio si dabi Ọlọrun, bi angeli Oluwa niwaju wọn.
9Yio si ṣe li ọjọ na, emi o wá lati pa gbogbo awọn orilẹ-ède run ti o wá kọjuja si Jerusalemu.
10Emi o si tú ẹmi ore-ọfẹ ati ẹbẹ sori ile Dafidi ati sori Jerusalemu: nwọn o si ma wò mi ẹniti nwọn ti gún li ọ̀kọ, nwọn o si ma ṣọ̀fọ rẹ̀, gẹgẹ bi enia ti nṣọ̀fọ fun ọmọ ọkunrin rẹ̀ kanṣoṣo, nwọn o si wà ni ibanujẹ, bi ẹniti mbanujẹ fun akọbi rẹ̀.
11Li ọjọ na li ọ̀fọ nlanlà yio wà ni Jerusalemu, gẹgẹ bi ọ̀fọ Hadadrimmoni li afonifoji Megiddoni.
12Ilẹ na yio ṣọ̀fọ, idile idile lọtọ̀tọ; idile Dafidi lọ́tọ̀; ati awọn aya wọn lọ́tọ̀; idile Natani lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọtọ̀.
13Idile Lefi lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀; idile Ṣimei lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀.
14Gbogbo awọn idile ti o kù, idile idile lọtọ̀tọ, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Sek 12: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.