Ẹniti o ro ilẹ rẹ̀ li a o fi onjẹ tẹlọrun: ṣugbọn ẹniti ntọ̀ enia-lasan lẹhin ni oye kù fun. Enia buburu fẹ ilu-odi awọn enia buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo so eso. Irekọja ète enia buburu li a fi idẹkùn rẹ̀: ṣugbọn olododo yio yọ kuro ninu ipọnju. Nipa ère ẹnu enia li a o fi ohun rere tẹ ẹ lọrun: ère-iṣẹ ọwọ enia li a o si san fun u. Ọ̀na aṣiwere tọ li oju ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o fetisi ìgbimọ li ọlọgbọ́n. Ibinu aṣiwere kò pẹ imọ̀: ṣugbọn amoye enia bò itiju mọlẹ. Ẹniti o sọ otitọ, o fi ododo hàn jade; ṣugbọn ẹlẹri eke, ẹ̀tan. Awọn kan mbẹ ti nyara sọ̀rọ lasan bi igunni idà; ṣugbọn ahọn ọlọgbọ́n, ilera ni. Ete otitọ li a o mu duro lailai; ṣugbọn ahọn eke, ìgba diẹ ni. Ẹtan wà li aiya awọn ti nrò ibi: ṣugbọn fun awọn ìgbimọ alafia, ayọ̀ ni. Kò si ibi kan ti yio ba olododo; ṣugbọn awọn enia buburu ni yio kún fun ibi. Irira loju Oluwa li ahọn eke; ṣugbọn awọn ti nṣe rere ni didùn-inu rẹ̀. Ọlọgbọ́n enia pa ìmọ mọ; ṣugbọn aiya awọn aṣiwere nkede iwere.
Kà Owe 12
Feti si Owe 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 12:11-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò