Num 36

36
Ogún Àwọn Obinrin Abilékọ
1AWỌN baba àgba ti idile awọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ti idile awọn ọmọ Josefu, sunmọtosi, nwọn si sọ niwaju Mose, ati niwaju awọn olori, awọn baba àgba awọn ọmọ Israeli:
2Nwọn si wipe, OLUWA ti paṣẹ fun oluwa mi lati fi keké pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli ni iní: a si fi aṣẹ fun oluwa mi lati ọdọ OLUWA wá lati fi ilẹiní Selofehadi arakunrin wa fun awọn ọmọ rẹ̀ obinrin.
3Bi a ba si gbé wọn niyawo fun ẹnikan ninu awọn ọmọkunrin ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli miran, nigbana ni a o gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní awọn baba wa, a o si fi kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà a kuro ninu ipín ilẹ-iní ti wa.
4Ati nigbati ọdún jubeli awọn ọmọ Israeli ba dé, nigbana li a o fi ilẹ-iní wọn kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba wa.
5Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, pe, Ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu fọ̀ rere.
6Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ nipa ti awọn ọmọbinrin Selofehadi, wipe, Ki nwọn ki o ṣe aya ẹniti o wù wọn; kiki pe, ninu idile ẹ̀ya baba wọn ni ki nwọn ki o gbeyawo si.
7Bẹ̃ni ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli ki yio yi lati ẹ̀ya de ẹ̀ya: nitori ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o le faramọ́ ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba rẹ̀:
8Ati gbogbo awọn ọmọbinrin, ti o ní ilẹ-iní ninu ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli, ki o ṣe aya fun ọkan ninu idile ẹ̀ya baba rẹ̀, ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o le ma jogún ilẹ-iní awọn baba rẹ̀.
9Bẹ̃ni ki ilẹ-iní ki o máṣe yi lati ẹ̀ya kan lọ si ẹ̀ya keji; ṣugbọn ki olukuluku ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli ki o faramọ́ ilẹ-iní tirẹ̀.
10Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọbinrin Selofehadi ṣe:
11Nitoripe a gbé Mala, Tirsa, ati Hogla, ati Milka, ati Noa, awọn ọmọbinrin Selofehadi niyawo fun awọn ọmọ arakunrin baba wọn.
12A si gbé wọn niyawo sinu idile awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu, ilẹ-ini wọn si duro ninu ẹ̀ya idile baba wọn.
13Wọnyi ni aṣẹ ati idajọ ti OLUWA palaṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati ọwọ́ Mose, ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Num 36: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀