Num 26
26
Ètò Ìkànìyàn Keji
1O SI ṣe lẹhin àrun na, ni OLUWA sọ fun Mose ati fun Eleasari alufa ọmọ Aaroni pe,
2Kà iye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, gbogbo awọn ti o le lọ si ogun ni Israeli.
3Mose ati Eleasari alufa si sọ fun wọn ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, lẹba Jordani leti Jeriko pe,
4Ẹ kà iye awọn enia na, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati fun awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá.
5Reubeni, akọ́bi Israeli: awọn ọmọ Reubeni; Hanoki, lati ọdọ ẹniti idile awọn ọmọ Hanoki ti wá: ti Pallu, idile awọn ọmọ Pallu:
6Ti Hesroni, idile awọn ọmọ Hesroni: ti Karmi, idile awọn ọmọ Karmi.
7Wọnyi ni idile awọn ọmọ Reubeni: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanlelogun o le ẹgbẹsan o din ãdọrin.
8Ati awọn ọmọ Pallu; Eliabu.
9Ati awọn ọmọ Eliabu; Nemueli, ati Datani, ati Abiramu. Eyi ni Datani ati Abiramu na, ti nwọn lí okiki ninu ijọ, ti nwọn bá Mose ati Aaroni jà ninu ẹgbẹ Kora, nigbati nwọn bá OLUWA jà.
10Ti ilẹ si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì pọ̀ pẹlu Kora, nigbati ẹgbẹ na fi kú, nigbati iná fi run awọn ãdọtalerugba ọkunrin, ti nwọn si di àmi kan.
11Ṣugbọn awọn ọmọ Kora kò kú.
12Awọn ọmọ Simeoni bi idile wọn: ti Nemueli, idile Nemueli: ti Jamini, idile Jamini: ti Jakini, idile Jakini:
13Ti Sera, idile Sera: ti Ṣaulu, idile Ṣaulu.
14Wọnyi ni idile awọn ọmọ Simeoni, ẹgba mọkanla o le igba.
15Awọn ọmọ Gadi bi idile wọn: ti Sefoni, idile Sefoni: ti Haggi, idile Haggi: ti Ṣuni, idile Ṣuni:
16Ti Osni, idile Osni: ti Eri, idile Eri:
17Ti Arodu, idile Arodu: ti Areli, idile Areli.
18Wọnyi ni idile awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta.
19Awọn ọmọ Juda, ni Eri ati Onani: ati Eri ati Onani kú ni ilẹ Kenaani.
20Ati awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn; ti Ṣela, idile Ṣela: ti Peresi, idile Peresi: ti Sera, idile Sera.
21Awọn ọmọ Peresi; ti Hesroni, idile Hesroni: ti Hamulu, idile Hamulu.
22Wọnyi ni idile Juda gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejidilogoji o le ẹdẹgbẹta.
23Awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn: ti Tola, idile Tola: ti Pufa, idile Pufa:
24Ti Jaṣubu, idile Jaṣubu: ti Ṣimroni, idile Ṣimroni.
25Wọnyi ni idile Issakari gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le ọdunrun.
26Awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn: ti Seredi, idile Seredi: ti Eloni, idile Eloni: ti Jaleeli, idile Jaleeli.
27Wọnyi ni idile awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ mẹta o le ẹdẹgbẹta.
28Awọn ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn: Manasse ati Efraimu.
29Awọn ọmọ Manasse: ti Makiri, idile Makiri: Makiri si bi Gileadi: ti Gileadi, idile awọn ọmọ Gileadi.
30Wọnyi li awọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, idile Ieseri: ti Heleki, idile Heleki:
31Ati ti Asrieli, idile Asrieli: ati ti Ṣekemu, idile Ṣekemu:
32Ati Ṣemida, idile awọn ọmọ Ṣemida: ati ti Heferi, idile awọn ọmọ Heferi.
33Selofehadi ọmọ Heferi kò si lí ọmọkunrin, bikọse ọmọbinrin: orukọ awọn ọmọbinrin Selofehadi a ma jẹ Mala, ati Noa, ati Hogla, Milka, ati Tirsa.
34Wọnyi ni idile Manasse, ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin.
35Wọnyi li awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣutela, idile awọn ọmọ Ṣutela: ti Bekeri, idile awọn ọmọ Bekeri: ti Tahani, idile awọn ọmọ Tahani.
36Wọnyi li awọn ọmọ Ṣutela: ti Erani, idile awọn ọmọ Erani.
37Wọnyi ni idile awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le ẹdẹgbẹta. Wọnyi li awọn ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn.
38Awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ti Bela, idile awọn ọmọ Bela: ti Aṣbeli, idile awọn ọmọ Aṣbeli: ti Ahiramu, idile awọn ọmọ Ahiramu.
39Ti Ṣefamu, idile awọn ọmọ Ṣufamu: ti Hufamu, idile awọn ọmọ Hufamu.
40Awọn ọmọ Bela si ni Ardi ati Naamani: ti Ardi, idile awọn ọmọ Ardi: ati ti Naamani, idile awọn ọmọ Naamani.
41Wọnyi li awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ẹgbẹjọ.
42Wọnyi li awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣuhamu, idile awọn ọmọ Ṣuhamu. Wọnyi ni idile Dani gẹgẹ bi idile wọn.
43Gbogbo idile awọn ọmọ Ṣuhamu, gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le irinwo.
44Ti awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn: ti Imna, idile awọn ọmọ Imna: ti Iṣfi, idile awọn ọmọ Iṣfi: ti Beria, idile awọn ọmọ Beria.
45Ti awọn ọmọ Beria: ti Heberi, idile awọn ọmọ Heberi: ti Malkieli, idile awọn ọmọ Malkieli.
46Orukọ ọmọ Aṣeri obinrin a si ma jẹ́ Sera.
47Wọnyi ni idile awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn; nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje.
48Ti awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn: ti Jaseeli, idile awọn ọmọ Jaseeli: ti Guni, idile awọn ọmọ Guni:
49Ti Jeseri, idile awọn ọmọ Jeseri: ti Ṣillemu, idile awọn ọmọ Ṣillemu.
50Wọnyi ni idile ti Naftali gẹgẹ bi idile wọn: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le egbeje.
51Wọnyi li a kà ninu awọn ọmọ Israeli, ọgbọ̀n ọkẹ, o le ẹgbẹsan o din ãdọrin.
52OLUWA si sọ fun Mose pe,
53Fun awọn wọnyi ni ki a pín ilẹ na ni iní gẹgẹ bi iye orukọ.
54Fun awọn ti o pọ̀ ni ki iwọ ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun awọn ti o kére ni ki iwọ ki o fi diẹ fun: ki a fi ilẹ-iní olukuluku fun u gẹgẹ bi iye awọn ti a kà ninu rẹ̀.
55Ṣugbọn kèké li a o fi pín ilẹ na: gẹgẹ bi orukọ ẹ̀ya awọn baba wọn ni ki nwọn ki o ní i.
56Gẹgẹ bi kèké ni ki a pín ilẹ-iní na lãrin awọn pupọ̀ ati diẹ.
57Wọnyi si li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, gẹgẹ bi idile wọn: ti Gerṣoni, idile awọn ọmọ Gerṣoni: ti Kohati, idile awọn ọmọ Kohati: ti Merari, idile awọn ọmọ Merari.
58Wọnyi ni idile awọn ọmọ Lefi: idile awọn ọmọ Libni, idile awọn ọmọ Hebroni, idile awọn ọmọ Mali, idile awọn ọmọ Muṣi, idile awọn ọmọ Kora. Kohati si bi Amramu.
59Orukọ aya Amramu a si ma jẹ́ Jokebedi, ọmọbinrin Lefi, ti iya rẹ̀ bi fun Lefi ni Egipti: on si bi Aaroni, ati Mose, ati Miriamu arabinrin wọn fun Amramu.
60Ati fun Aaroni li a bi Nadabu ati Abihu, Eleasari ati Itamari.
61Ati Nadabu ati Abihu kú, nigbati nwọn mú iná ajeji wá siwaju OLUWA.
62Awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanla o le ẹgbẹrun, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan ati jù bẹ̃ lọ: nitoripe a kò kà wọn kún awọn ọmọ Israeli, nitoriti a kò fi ilẹ-iní fun wọn ninu awọn ọmọ Israeli.
63Wọnyi li awọn ti a kà lati ọwọ́ Mose ati Eleasari alufa wá, awọn ẹniti o kà awọn ọmọ Israeli ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.
64Ṣugbọn ninu wọnyi kò sì ọkunrin kan ninu awọn ti Mose ati Aaroni alufa kà, nigbati nwọn kà awọn ọmọ Israeli li aginjù Sinai.
65Nitoriti OLUWA ti wi fun wọn pe, Kíku ni nwọn o kú li aginjù. Kò si kù ọkunrin kan ninu wọn, bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, ati Joṣua ọmọ Nuni.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Num 26: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.