YouVersion Logo
Search Icon

Mat 7:24, 25, 26, 27, 28, 29

Mat 7:24 YBCV

Nitorina ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti o ba si ṣe wọn, emi o fi wé ọlọ́gbọn enia kan, ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori àpata

Mat 7:25 YBCV

Òjo si rọ̀, ikún omi si dé, afẹfẹ si fẹ́ nwọn si bìlu ile na; ko si wó, nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori àpata.

Mat 7:26 YBCV

Ẹnikẹni ti o ba si gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti kò si ṣe wọn, on li emi o fi wé aṣiwere enia kan ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori iyanrin

Mat 7:27 YBCV

Òjo si rọ̀, ikún omi si de, afẹfẹ si fẹ́, nwọn si bìlu ile na, o si wó; iwó rẹ̀ si pọ̀ jọjọ.

Mat 7:28 YBCV

Nigbati o si ṣe ti Jesu pari gbogbo òrọ wọnyi tan, ẹnu yà gbogbo enia si ẹkọ́ rẹ̀

Mat 7:29 YBCV

Nitori o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, ki si iṣe bi awọn akọwe.