YouVersion Logo
Search Icon

Mat 23:1, 2, 3, 4, 5, 6, 7, 8, 9, 10, 11, 12

Mat 23:1 YBCV

NIGBANA ni Jesu wi fun ijọ enia, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀

Mat 23:2 YBCV

Pe, Awọn akọwe pẹlu awọn Farisi joko ni ipò Mose

Mat 23:3 YBCV

Nitorina ohunkohun gbogbo ti nwọn ba wipe ki ẹ kiyesi, ẹ mã kiyesi wọn ki ẹ si mã ṣe wọn; ṣugbọn ẹ má ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: nitoriti nwọn a ma wi, ṣugbọn nwọn ki iṣe.

Mat 23:4 YBCV

Nitori nwọn a di ẹrù wuwo ti o si ṣoro lati rù, nwọn a si gbé e kà awọn enia li ejika; ṣugbọn awọn tikarawọn ko jẹ fi ika wọn kàn ẹrù na.

Mat 23:5 YBCV

Ṣugbọn gbogbo iṣẹ wọn ni nwọn nṣe nitori ki awọn enia ki o ba le ri wọn: nwọn sọ filakteri wọn di gbigbòro, nwọn fi kún iṣẹti aṣọ wọn.

Mat 23:6 YBCV

Nwọn fẹ ipò ọlá ni ibi ase, ati ibujoko ọla ni sinagogu

Mat 23:7 YBCV

Ati ikíni li ọjà, ati ki awọn enia mã pè wọn pe, Rabbi, Rabbi.

Mat 23:8 YBCV

Ṣugbọn ki a máṣe pè ẹnyin ni Rabbi: nitoripe ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin.

Mat 23:9 YBCV

Ẹ má si ṣe pè ẹnikan ni baba nyin li aiye: nitori ẹnikan ni Baba nyin, ẹniti mbẹ li ọrun.

Mat 23:10 YBCV

Ki a má si ṣe pè nyin ni olukọni: nitori ọkan li Olukọni nyin, ani Kristi.

Mat 23:11 YBCV

Ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin, on ni yio jẹ iranṣẹ nyin.

Mat 23:12 YBCV

Ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ li a o gbé ga.