YouVersion Logo
Search Icon

Mat 21:1, 2, 3, 4, 5, 6, 7, 8, 9, 10, 11

Mat 21:1 YBCV

NIGBATI nwọn sunmọ eti Jerusalemu, ti nwọn de Betfage li òke Olifi, nigbana ni Jesu rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji lọ.

Mat 21:2 YBCV

O wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin, lọgan ẹnyin o ri kẹtẹkẹtẹ kan ti a so ati ọmọ rẹ̀ pẹlu: ẹ tú wọn, ki ẹ si fà wọn fun mi wá.

Mat 21:3 YBCV

Bi ẹnikẹni ba si wi nkan fun nyin, ẹnyin o wipe, Oluwa ni ifi wọn ṣe; lọgán ni yio si rán wọn wá.

Mat 21:4 YBCV

Gbogbo eyi li a ṣe, ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu wolĩ wá ki o le ṣẹ, pe

Mat 21:5 YBCV

Ẹ sọ fun ọmọbinrin Sioni pe, Kiyesi i, Ọba rẹ mbọ̀ wá sọdọ rẹ, o ni irẹlẹ, o joko lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ.

Mat 21:6 YBCV

Awọn ọmọ-ẹhin na si lọ, nwọn ṣe bi Jesu ti wi fun wọn.

Mat 21:7 YBCV

Nwọn si fà kẹtẹkẹtẹ na wá, ati ọmọ rẹ̀, nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹhin wọn, nwọn si gbé Jesu kà a.

Mat 21:8 YBCV

Ọ̀pọ ijọ enia tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na; ẹlomiran ṣẹ́ ẹka igi wẹ́wẹ́, nwọn si fún wọn si ọ̀na.

Mat 21:9 YBCV

Ijọ enia ti nlọ niwaju, ati eyi ti ntọ̀ wọn lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa; Hosanna loke ọrun.

Mat 21:10 YBCV

Nigbati o de Jerusalemu, gbogbo ilu mì titi, wipe, Tani yi?

Mat 21:11 YBCV

Ijọ enia si wipe, Eyi ni Jesu wolĩ, lati Nasareti ti Galili.