YouVersion Logo
Search Icon

Mat 16:1, 2, 3, 4, 5, 6, 7, 8, 9, 10, 11, 12, 13, 14, 15, 17, 18, 19, 20

Mat 16:1 YBCV

AWỌN Farisi pẹlu awọn Sadusi si wá, nwọn ndán a wò, nwọn si nfẹ ki o fi àmi hàn fun wọn lati ọrun wá.

Mat 16:2 YBCV

Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Nigbati ó ba di aṣalẹ, ẹnyin a wipe, Ọjọ ó dara: nitoriti oju ọrun pọ́n.

Mat 16:3 YBCV

Ati li owurọ̀ ẹnyin a wipe, Ọjọ kì yio dara loni, nitori ti oju ọrun pọ́n, o si ṣú dẹ̀dẹ. A! ẹnyin agabagebe, ẹnyin le mọ̀ àmi oju ọrun; ṣugbọn ẹnyin ko le mọ̀ àmi akokò wọnyi?

Mat 16:4 YBCV

Iran buburu ati panṣaga nfẹ àmi; a kì yio si fi àmi fun u, bikoṣe àmi ti Jona wolĩ. O si fi wọn silẹ, o kuro nibẹ.

Mat 16:5 YBCV

Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si de apakeji, nwọn gbagbé lati mu akara lọwọ.

Mat 16:6 YBCV

Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹ si mã sọra niti iwukara awọn Farisi ati ti awọn Sadusi.

Mat 16:7 YBCV

Nwọn si mbá ara wọn ṣaroye, wipe, Nitoriti awa ko mu akara lọwọ ni.

Mat 16:8 YBCV

Nigbati Jesu si woye, o wi fun wọn pe, Ẹnyin onigbagbọ́ kekere, ẽṣe ti ẹnyin fi mba ara nyin ṣaroye, nitoriti ẹnyin ko mu akara lọwọ?

Mat 16:9 YBCV

Kò iti yé nyin di isisiyi, ẹnyin kò si ranti iṣu akara marun ti ẹgbẹdọgbọn enia, ati iye agbọ̀n ti ẹnyin si kójọ.

Mat 16:10 YBCV

Ẹ kò si ranti iṣu akara meje ti ẹgbaji enia, ati iye agbọ̀n ti ẹnyin kójọ?

Mat 16:11 YBCV

Ẽha ti ṣe ti kò fi yé nyin pe, emi kò ti itori akara sọ fun nyin pe, ẹ kiyesi ara nyin niti iwukara ti awọn Farisi ati ti awọn Sadusi.

Mat 16:12 YBCV

Nigbana li o to yé wọn pe, ki iṣe iwukara ti akara li o wipe ki nwọn kiyesara rẹ̀, ṣugbọn ẹkọ́ ti awọn Farisi ati ti awọn Sadusi.

Mat 16:13 YBCV

Nigbati Jesu de igberiko Kesarea Filippi, o bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẽre, wipe, Tali awọn enia nfi emi Ọmọ-enia ipe?

Mat 16:14 YBCV

Nwọn si wi fun u pe, Omiran ní, Johanu Baptisti; omiran wipe, Elijah; awọn ẹlomiran ni, Jeremiah, tabi ọkan ninu awọn woli.

Mat 16:15 YBCV

O bi wọn lẽre, wipe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè?

Mat 16:17 YBCV

Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Alabukun-fun ni iwọ Simoni Ọmọ Jona: ki iṣe ẹran ara ati ẹ̀jẹ li o sá fi eyi hàn ọ, ṣugbọn Baba mi ti mbẹ li ọrun.

Mat 16:18 YBCV

Emi si wi fun ọ pẹlu pe, Iwọ ni Peteru, ori apata yi li emi ó si kọ ijọ mi le; ẹnu-ọ̀na ipo-oku kì yio si le bori rẹ̀.

Mat 16:19 YBCV

Emi ó si fun ọ ni kọkọrọ ijọba ọrun: ohunkohun ti iwọ ba dè li aiye, a o si dè e li ọrun: ohunkohun ti iwọ ba tú li aiye, a o si tú u li ọrun.

Mat 16:20 YBCV

Nigbana li o kìlọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn ki o màṣe sọ fun ẹnikan pe, on ni Kristi na.