YouVersion Logo
Search Icon

Mat 15:21, 22, 23, 24, 25, 26, 27, 28, 29, 30, 31, 32, 33, 34, 35, 36, 37, 38, 39

Mat 15:21 YBCV

Jesu si ti ibẹ̀ kuro, o si lọ si àgbegbe Tire on Sidoni.

Mat 15:22 YBCV

Si wò o, obinrin kan ara Kenaani ti ẹkùn na wá, o si kigbe pè e, wipe, Oluwa, iwọ ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi; ọmọbinrin mi li ẹmi èṣu ndá lóró gidigidi.

Mat 15:23 YBCV

Ṣugbọn kò si dá a lohùn ọrọ kan. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, nwọn bẹ̀ ẹ, wipe, Rán a lọ kuro, nitoriti o nkigbe tọ̀ wá lẹhin.

Mat 15:24 YBCV

Ṣugbọn o dahùn wipe, A kò rán mi, bikoṣe si awọn agutan ile Israeli ti o nù.

Mat 15:25 YBCV

Nigbana li o wá, o si tẹriba fun u, wipe, Oluwa, ràn mi lọwọ.

Mat 15:26 YBCV

Ṣugbọn o dahùn, wipe, Ko tọ́ ki a mu akara awọn ọmọ, ki a fi i fun ajá.

Mat 15:27 YBCV

O si wipe, Bẹni, Oluwa: awọn ajá a ma jẹ ninu ẹrún ti o ti ori tabili oluwa wọn bọ́ silẹ.

Mat 15:28 YBCV

Nigbana ni Jesu dahùn o si wi fun u pe, Obinrin yi, igbagbọ́ nla ni tirẹ: ki o ri fun ọ gẹgẹ bi iwọ ti nfẹ. A si mu ọmọbinrin rẹ̀ larada ni wakati kanna.

Mat 15:29 YBCV

Jesu si ti ibẹ̀ kuro, o wá si eti okun Galili, o gùn ori òke lọ, o si joko nibẹ̀.

Mat 15:30 YBCV

Ọpọ enia si tọ̀ ọ wá ti awọn ti amukun, afọju, odi, ati arọ, ati ọ̀pọ awọn miran, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o si mu wọn larada

Mat 15:31 YBCV

Tobẹ̃, ti ẹnu yà ijọ enia na, nigbati nwọn ri ti odi nfọhùn, ti arọ ndi ọ̀tọtọ, ti amukun nrìn, ti afọju si nriran: nwọn si yìn Ọlọrun Israeli logo.

Mat 15:32 YBCV

Jesu si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ọdọ, o si wipe, Anu ijọ enia nṣe mi, nitoriti o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn ko si li ohun ti nwọn o jẹ: emi kò si fẹ rán wọn lọ li ebi, ki ãrẹ̀ má bà mu wọn li ọ̀na.

Mat 15:33 YBCV

Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo li awa o ti ri akara to li aginjù, ti yio fi yó ọ̀pọ enia yi?

Mat 15:34 YBCV

Jesu wi fun wọn pe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? Nwọn wipe, Meje, pẹlu ẹja kekeke diẹ.

Mat 15:35 YBCV

O si paṣẹ ki a mu ijọ enia joko ni ilẹ.

Mat 15:36 YBCV

O si mu iṣu akara meje, ati ẹja na, o sure, o bù u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si fifun ijọ enia.

Mat 15:37 YBCV

Gbogbo nwọn si jẹ, nwọn si yó: nwọn si kó ajẹkù ti o kù jọ, agbọ̀n meje kún.

Mat 15:38 YBCV

Awọn ti o jẹun to ẹgbaji ọkunrin, li aikà awọn obinrin ati awọn ọmọde.

Mat 15:39 YBCV

O si rán ijọ enia lọ; o si bọ́ sinu ọkọ̀, o lọ si ẹkùn Magdala.