YouVersion Logo
Search Icon

Mat 15:1, 2, 3, 4, 5, 6, 7, 8, 9, 10, 11, 12, 13, 14, 16, 17, 18, 19, 20

Mat 15:1 YBCV

NIGBANA li awọn akọwe ati awọn Farisi ti Jerusalemu tọ̀ Jesu wá, wipe

Mat 15:2 YBCV

Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ fi nrú ofin atọwọdọwọ awọn alàgba? nitoriti nwọn kì iwẹ̀ ọwọ́ wọn nigbati nwọn ba njẹun.

Mat 15:3 YBCV

Ṣugbọn o dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin pẹlu nfi ofin atọwọdọwọ nyin rú ofin Ọlọrun?

Mat 15:4 YBCV

Nitori Ọlọrun ṣòfin, wipe, Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ati ẹniti o ba sọrọ baba ati iya rẹ̀ ni buburu, ẹ jẹ ki o kú ikú rẹ̀.

Mat 15:5 YBCV

Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ẹnikẹni ti o ba wi fun baba tabi iya rẹ̀ pe, Ẹbùn li ohunkohun ti iwọ iba fi jère lara mi

Mat 15:6 YBCV

Ti ko si bọ̀wọ fun baba tabi iya rẹ̀, o bọ́. Bẹ̃li ẹnyin sọ ofin Ọlọrun di asan nipa ofin atọwọdọwọ nyin.

Mat 15:7 YBCV

Ẹnyin agabagebe, otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti nyin, wipe

Mat 15:8 YBCV

Awọn enia yi nfi ẹnu wọn sunmọ mi, nwọn si nfi ète wọn bọla fun mi; ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi.

Mat 15:9 YBCV

Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ.

Mat 15:10 YBCV

O si pè ijọ enia, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ki o si ye nyin

Mat 15:11 YBCV

Ki iṣe ohun ti o wọni li ẹnu lọ, ni isọ enia di alaimọ́; bikoṣe eyi ti o ti ẹnu jade wá, eyini ni isọ enia di alaimọ́.

Mat 15:12 YBCV

Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ pe, awọn Farisi binu lẹhin igbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ yi?

Mat 15:13 YBCV

O si dahùn, o wi fun wọn pe, Igikigi ti Baba mi ti mbẹ li ọrun kò ba gbìn, a o fà a tu kuro.

Mat 15:14 YBCV

Ẹ jọwọ wọn si: afọju ti nfọ̀nahàn afọju ni nwọn. Bi afọju ba si nfọnahàn afọju, awọn mejeji ni yio ṣubu sinu ihò.

Mat 15:16 YBCV

Jesu si wipe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye sibẹ?

Mat 15:17 YBCV

Ẹnyin ko mọ̀ pe, ohunkohun ti o ba bọ si ẹnu lọ si inu, a si yà a jade?

Mat 15:18 YBCV

Ṣugbọn nkan wọnni ti o ti ẹnu jade, inu ọkàn li o ti wá; nwọn a si sọ enia di alaimọ́.

Mat 15:19 YBCV

Nitori lati inu ọkàn ni iro buburu ti ijade wá, ipania, panṣaga, àgbere, olè, ẹ̀rí èké ati ọ̀rọ buburu

Mat 15:20 YBCV

Ohun wọnyi ni isọ enia di alaimọ́: ṣugbọn ki a jẹun li aiwẹwọ́ kò sọ enia di alaimọ́.